Smiley face

Alakatakiti esin Islam (ISIS) se meje (7) ninu awon omo ogun won ninu omi gbigbona: Ki ni idi abajo?


Sebi Yoruba ni adiẹ kii jefun ara won ni? Oro ko ri bẹẹ pelu awon omo alakatakiti esin Islam, ISIS.
Onidajo Sharia
Awon omo ogun lakatakiti esin islam ti won wa ni agbegbe Iraq ati Syria ti a mo si ISIS ti se meje ninu awon omo ogun won ninu omi gbigbona bi igba ti eniyan bọ ẹran.

Ohun to fa sababi naa ni ẹsun ti won fi kan awon meje naa wi pe won sa seyin loju ija to gbona jainjain kan to waye niluu Sharqat to wa Salahuddin  ni orileede 
Iraq
 
Ojo Mọnde (04/07/2016) to koja yii ni won sè awon omo ogun alakatakiti esin naa leyin ti won ti dewon lọwọ ati lẹsẹ bi igba ti eniyan de ẹran ileya. 
 
Won tilẹ tun fi okuta fọ awon kan lori nita gbangba lati fi won sẹsin aye ki won to ko won sinu omi gbigbona ti n wo yayaaya bi omi okun
Bakan naa la tun gbo wi pe, awon eniyan bi mokandinlogun (19) ni won pa ninu awon eniyan won losu to koja latari wi pe won sojo loju ogun.








Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment