Smiley face

Itan atenudenu: ORUN ATI OSUPA

Nígbà ìwásẹ̀, ọba òde ọ̀run níse alákoso ohun gbogbo ohun, ìkáwọ́ rẹ̀ ṣì ni gbogbo ohun tí a dá wà. Oba òde òrun ní ìyàwó , ósì tún bí ọmọ méjì.

Orun àti Osùpá ni ọmọ méjì tí ọba ode ọ̀run bí. Orùn àti òsùpá fẹ́ràn ara wọn gaani, tí ó jẹ́ wí pé bí òsùpá ò bá ṣí nílé òrùn kòní jẹun àfi ìgbà tí òsùpá bá dé.
Bẹ́ẹ̀ nọ sì ni òsùpá bí òrùn kò bá dé kò ní jẹun. Ní ọjọ kan ọba òde ọ̀run ránsé sí òsùpá àti òrùn ọmọ rẹ wì pè kí wọn wà rí òhun. Nígbàti wọn dé bè, Oba òde ọ̀run sọ fún wọn wí pé òhun fẹ rìn irìnàjò kan tí yóò sì pẹ́ kí òhun tó padà.


O ní kí òsùpá àti òrùn lọ fi oríkorí kí wọn se àpérò ẹni tí yóò delé de òhun tí òhun bá wà ní ìrìnàjò.
Wọ̀n dúpé lówó bàbá wọn , wọn sì se ìlérí láti se gẹ́gẹ́ bí bàbá wọn ti sọ.
Ní Ojọ́rú ọ̀sẹ̀ kan náà, osùpá àti òrùn fi ojú kan ra sùgbón ọ̀rọ̀ ò wọ̀ láàrín àwọn méjèèjì lérí ẹni tí yóò délé nígbàtí bàbá wọn bá lọ.

Osùpá ní òhun ọkọ ẹgbàágbèje ìràwọ̀ ni yóò delé de bàbá àwọn.
Béèni òrùn tutọ́ sókè fojúgbàá wí pé òhun ìmólè ọmọ aráyé ni yóò delé de bàbá àwọn.
O ní láì sí èmi òrùn inú òkùnkùn biribiri ni ayé kò bá wà. O ní èmi àfi ojojúmó dára bí egbin.
Osùpá sọ wí pé tí o bá rí béè ọmọ aráyé òní máà sọ wí pé isẹ́ lò òsùpá se lájùlé ọ̀run.

O ní òhun ni yóò delé de bàbá wọn. Bí wọ́n ti ń gba ọ̀rọ̀ náà bí ẹni gba igbá ọtí re, títí ó fi di ìjà.
Osùpá lu òrùn ní ìlú ẹni lu bàrà, òrùn pa òsùpá nípa ejò àìjẹ. Nígbátì bàbá wọn gbọ́ sí ọ̀rọ̀ náà inú rẹ bàjé.

O ní kí wọn pe àwọn méjèèji wá sí àgbàlà Olódùmarè.
Ní ibẹ̀ ló ti jẹ kóyé wọn wí pé òhun ọba òde ọ̀run ní se alákòso ọ̀sán àti òru.
O ní ní ìdí èyí òhun yóò pin ìlú náà sí méjì. O ní kí òsùpá máà jọba lérí òru , ó sì ní kí òrùn máà jọba lóri ọ̀sán wọn kò sì gbọdọ̀ fi ojú kan ra gẹ́gẹ́ bí ìjìyà ẹ̀sẹ̀ wọn.

Ní ọjọ́ yíí inú òsùpá àti òrùn bàjẹ́ nítorí wọn kòní fo jú kan ra mọ́ àti wí pé àyè àti má se bí ẹbí ti dópin.

Igbàkúgbá tí òrùn àbí òsùpá báti rántí ìdájó yii, nínú ọdún wọn a máa sunkún lọ́pọ̀lọpọ̀, ekún wọ̀nyí ni àwa ọmọ ènìyàn ńpè ní ọjọ́.


EKO INU ITAN YII
• O ko wa wi pe kii a maa ja si asan aye
• O ko wa wi pe ki a maa fi ogbon si igbese wa gbogbo
• o si ko wa wi pe ife laarin ebi se pataki osi se koko




Orisun: Akinlade Frank Omoolowo Bank/ Yorùbá Dùn
















Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment