#ayeOlabisiK10
Si Olootu Yoruba Dun,
MO KI GBOGBO ILE.
Mo ki yin ku aduroti ati
adura ti ẹ n gba fun mi lori ọrọ aye mi, Olorun oba ko ni dayin da ọrọ aye yin.
E ma binu wi pe mi o tete pada bọ. Olorun ko ni jẹ ka ri wahala.
Gẹgẹ bi mo ti n sọ tẹlẹ, ẹni
gbodo mi lọrọ mi, iduro ko si ibẹrẹ ko si. Amọ mo dupe wi pe emi naa re e lonii. Mo si gba wi pe Olorun ti n ba mi
se lati igba yii wa, ti ko jẹ ki ẹ̀mí
mi bọ si ọwọ awon amokunseka yoo tun ba mi se delẹdelẹ. Amin
ISONISOKI AWON LETA MI
ATIJO
Ọpọlọpọ lo se alabapade
leta mi fun igba akọkọ, ki oye ọrọ mi le ye won, ẹ jẹ n sare salaye ẹni ti mo jẹ
gan-an nipato ati isonisoki awon leta mi to ti kọ ja.
Olabisi ni oruko mi, mo n
sisẹ ni ile ise agbasẹse kan, mo si nife isẹ mi pupo nitori isẹ gidi to lowo
lori ni. Awon owó ti mo n ri ni mo fi n toju iya mi ati awon aburo mi, tori mi
o ni baba mo.
Sugbon nigba to ya, ọga
kan ti won gbe wa sibi ise mi ni dandan, oun fe ba mi lajọsepọ.
Mo kọjalẹ fun-un. O da mi
duro lenu isẹ. Bakan naa lo fi olopaa mu mi wi pe mo gbe faili ile isẹ pamọ
lati se ile isẹ wa ni ijamba, ati lati je ki ile ise wa padanu ọpọlọpọ owó
nitori faili awon ti won gbe kongila fun wa ni. Ọrọ yii lo si gbe mi de agọ
olopaa.
0 comments:
Post a Comment