ẸFỌN
JẸ MI LAGỌ ỌLỌPAA
Mo
sun ẹyin ganta mọjumọ ọjọ keji. Ẹfon jẹ mi tan kilẹ to o mọ. Nigba to di ọjọ
keji, awon ọlọpaa tẹle mi délé wa lati lọ ṣe ayẹwo.
Won
tu gbogbo ile wa, won ko ri ohun to jọmọ ẹru ile isẹ wa kankan nibẹ.
Se
ẹ ko gbagbe wi pe mo ni ọrọ ti de olu ile isẹ wa ni Abuja. Won si ni dandan
awon o gbe mi lọ si ile ẹjọ ti mo ba kọ lati gbe faili yii silẹ. Ile ẹjọ kẹ?
Emi ti n ti n rowo jeun kanu, ibo ni mo ti fẹ rowo sẹjọ.
Aya mi n ja, se ki i
se wi pe olododo yoo ku sipo ika bayii? Bawo ni mo se fẹ sọrọ aye mi gan-an?
Lehin igba ti awon olopaa gbon ile mi wo yẹbẹyẹbẹ tan, won mu mi pada si agọ ọlọpaa
pẹlu awon eniyan mi ti won tele mi pẹlu.
Lẹyinọrẹyin,
won gba beeli mi nigba ti awon oniduro mi ba mi tọwọ bọwe pẹlu owó. Ni agọ olopaa
ni won si ti fi iwe ipejọ le mi lọwọ. Won ni ti mo ba kọ lati lo gbe faili yii
wa nibi ti mo gbesi, a jẹ wi pe ile ẹjọ ni yoo se idajọ mi bi o ti yẹ.
0 comments:
Post a Comment