Ẹ le ka itan igbesi aye Olabisi K to ti jade tẹlẹ NIBI ki ẹ to tesiwaju lati ka eleyii ki itan naa le yeyin daada
IKA LENIYAN…ENIYAN BURU
Lẹyin eyi, mo tun gbọ nipa rikiṣi ti ọga ti o ṣe mi nijamba tun un gbe kaná. Wọn sọ fun mi wi pe, o ti lẹdi-apo pọ pẹlu awon kan nibi isẹ mi lati tako mi ti ẹjo naa ba de ile ẹjọ.
Mo si mọ wi pe dandan ni ki awon osisẹ yii se tiẹ ki o ma ba yọwọ kilanko wọn kuro lẹnu isẹ.
Ẹkun ni mo n sun ni joojumọ aye mi, ti mo ba ti ji, ma tun lọ yẹwe ipẹjọ yii wo, omi ẹkun a tun jade loju mi poroporo bi egbére.
Orisiirisii éró lo n wa si mi lọkan. Ki n ma ti rise di asiko yii gan-an ì bá ti dara ju, iṣẹ ti mo ri naa lo da wahala si mi lorun yii. Nitori aa-fẹni-a-ko-fẹni. Pelu bi mo se bẹ ọga yii to, a fi igba to pitu ọwọ rẹ.
Ọjọ ti inu mi tun bajẹ ju ni ọjọ ti mo fi ọrọ yii lọ ọrẹ mi kan, ọrẹ mi yii pemi lọdẹ.
O ni emi ni mo n fi ìyà jẹ ara mi lainidi. O ni Olorun kò fìyà jẹ mi rara. O ni, "aye n seru ẹ kẹ, tuntun kọ ni ki ọga ma fẹ ọmọọsẹ ẹ."
O ni ẹni to yẹ ki n tun ma gba ni. Ki n ma gba tọwọ ẹ. O ni ṣe mo mọ ohun ti ọkọ afẹsọna mi n ṣe ni kọrọ ni? O ni mo tori wi pe mi ò fẹ dalẹ ifẹ, mo wa n fiya jẹra mi.
Ni ọjọ keji ni ọkọ afẹsọna mi wa sọ fun mi wi pe oun lọ si Pọtakọọti. O ni ise ti oun wa, won ti ni ki oun o wa fun ifọrọwanilẹnuwo . Mo sọ fun wi pe bawo ni ọran ti mo ko ara mi si, se yoo fi mi silẹ lo ni?
O fi da mi loju wi pe, nikete ti o un ba ti pari ifọrọwanilẹnuwo ni oun yoo ma bọ wale pada. Nigba ti o di ọjọ keji, ọkọ afẹsọna mi ba tiẹ lọ.
Ẹ tẹsiwaju ninu itan igbesi aye Olabisi K NIBI
0 comments:
Post a Comment