Smiley face

Bayii tun ni Olorun se n lo Osan onilu Ayefele

Apostle Seye Akinlabi
Seye Akinlabi ti gbogbo eniyan mọ si Ọsan onilu ti kuro lojẹwẹwẹ onilu ti n wa kọngọ ko to lùlù to dun seti araye.

Sebi gambari rẹ ti n gbe ni Sabo ọna jin.

O ti fi gba kan lùlù fun Yinka Ayefele ri, aimoye olorin ẹmi taye n fẹ lo je wi pe ilu Ọsan ni i dun ninu orin won to si n mu wọn gbayi nigba gbogbo.

Aimọye olorin ẹmi nilẹ yii ati loke okun ni Osan ti sọ di oloriire latari imọ ati iriri rẹ nidi isẹ orin-ẹmi to gbamuse nipase ileese rẹ.
Yato si gbigbe awọn olorin jade, Ọlọrun ti fi ifi ami-ororo yan Apostle Seye Akinlabi bayii lati maa se agbekalẹ ọdun orin iyin ọlọdọọdun fun itusilẹ ati igbega awọn ti wọn woju Oluwa fun iyanu oju-ẹsẹ.

Ẹ jẹ ki n mu yin wọ inu ọrọ Ọlọrun diẹ lọ. Won mu Poolu ati Saila wo ninu igbekun (Act 16:19-27). Akoko yii ni won liilo lati kepe Olorun lohun-rara ninu adura.

Sugbon kaka ki won gbadura, orin iyin ni won gbe soke si Oluwa. Ohun to si sẹlẹ ni isẹ iyanu nla.

Eyi wa lara iran ti Osan ba sise ati ise nla ti Olorun orun gbe le e lowo, lati mu awon eniyan gba itusile ninu igbekun nipase orin iyin.

Nibo wa ni Festival of Praise todun 2016 yii yoo ti waye? Awon eniyan Olorun wo ni won yoo wa nibi ipade naa? Akoko wo ni, ojo wo ni?
Ẹkunrẹrẹ alaye n bọ laipẹ.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment