Smiley face

Yoruba Dun: Itan igbesi aye Olabisi K (13)

#ayeOlabisiK13

Ẹ le ka itan igbesi aye Olabisi K to ti jade tẹlẹ NIBI ki ẹ to tesiwaju lati ka eleyii ki itan naa le yeyin daada

ỌGBỌN ỌLỌGBỌN 

Lẹyin eyi ni awon kan kọ mi wi pe ki n pe ọga mi yii, ki n so fun wi pe mo ti gba wi pe ko ba mi sun. Won ko mi lati gba ohùn rẹ silẹ sinu ẹrọ ti won fi n rikọọdu ohun.


Wọn ni ti o ba le sọrọ si mi lọwọ, won lo ti pari. Won ni ọna kan soso re e ti mo le fi bọ ninu wahala yii.

Lẹyin eyi, mo le rojọ ohun to sẹlẹ gan-an ki gbogbo awon eniyan ati ile ise ti mo n sise fun gbami gbo wi pe irọ ni pa mọ mi.

Mo rọ ọrọ yii, mo si ri ọgbọn ni bẹ. Mo pe oko afẹsọna mi lori ago, mo si se alaye yii fun un. O pe ọrẹ rẹ kan wi pe ko wa ba mi, ko le ran mi lọwọ lori awon ète ti mo fe lo ko ma ba je emi nikan.

Igba ti gbogbo eto pari, mo pe ago ọga mi yii titi, ẹ jẹ mọ wi pe ko gbe ago yii rara.

Eyi je ki irẹwẹsi ba ọkan mi, a bi o ti mo iru ọgbon ti mo fe lo fun un ni? Kilo le fa lati ma gbe ago mi? Mo ba gbero lati fi ọrọ ranse si ori ago rẹ. Ohun ti mo ko ranse re e:

"Ọga, Ẹ darijin mi. Ẹ̀mí mi ko gbe wahala yii mọ. Mo setan lati se ohun ti ẹ ba ni ki n ṣe."

Lehin wakati meji, atẹjisẹ kan wọle si ori ẹrọ mi pelu numbe ajoji.
"Ti o ba ji wi pe looto ni o fẹ bọ ninu wahala ti o ko ara rẹ si, pade mi n ile itura (mi o fe daruko ile itura naa) lago meje ale oni"

Igba ti mo ka ifiweranse yii ni mo to mo wi pe ọga mi ni, sugbon ko lo number ti mo mọ pẹlu rẹ.

Mo ti lọ duro de saaju ago meje to da fun mi yii ni ile itura naa. Ko pe ti mo de ile itura yii naa ni ọrẹ ọkọ afẹsọna mi naa de sibẹ. Eyi wa lara ète wa wi pe a ko ni jo rin papo. Igba to wọle, ko sebi ẹni wi pe o ri mi, emi naa ko wo ọdọ rẹ rara. 


Ẹ tẹsiwaju ninu itan igbesi aye Olabisi K NIBI
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment