Smiley face

Yoruba Dun: Itan igbesi aye Olabisi (14)

#ayeOlabisi14

Ẹ le ka itan igbesi aye Olabisi K to ti jade tẹlẹ NIBI ki ẹ to tesiwaju lati ka eleyii ki oye itan naa le yeyin daada.

Yoruba Dun: Itan igbesi aye Olabisi (14)
IBI AFOJU SI...

Nnkan bi isẹju marun-un ti kọja ago meje ni ale ọjọ naa, nọmba ajoji kan dun lori ago mi. Mo gbe ago yii seti. Mo ti n ro wi pe o le je pe ọga mi lo n pe mi. Bi mo se ro gẹlẹ naa ni, ọga mi lo n fi ago yii pe mi. 



Ọrẹ ọkọ afẹsọna mi n foju ẹgbẹ kan wo mi bi mo se n sọrọ lori ago. Ọga mi yii ni ki n ma bọ nita ile itura yii wi pe oun duro de mi nibẹ.
Mo sẹju si orẹ ọkọ afẹsọna mi wi pe ẹni taa wi ti de. Oun naa sẹju si mi wi pe ki lo ba nita nitori wi pe yara igbalejo ile itura yii ni awa mejeeji wa. 

Nigba ti mo deta, mi o ri mọto okunrin yii. Mo pe nọmba ọga mi lọgan, "kosi larọwọto" ni nomba sọ si mi leti. 

Mo pe nọmba ajoji to ma fi n pe mi, nọmba yen dun sugbon won o gbe lodi keji lohun. Mo duro, mo n wọtun, mo n tun wosi.

Mo se akiyesi wi pe tansi kan duro lọọkan niwaju mi, ti awon okunrin meji si wa ninu rẹ. 

Ọkan ninu won sọkalẹ wa ba mi. O ni se emi ni mo n duro de lagbaja bayi-bayi, mo ni bẹẹ ni. O ni ki n kalọ ki awon gbe mi lọ sibi ti ọga mi wa. 

Bi won se wi bayii tan, mi o mọ bimo se fẹ pada lo ke si ọrẹ ọkọ mi wi pe ibo miiran tun ni won tun un gbe mi lọ. 

Sugbon mo ro lọkan mi wi pe ma fi atẹjisẹ ranse si i bi a ba se n lọ. Ati wi pe ko tilẹ si ohun ti mo le se loju ẹsẹ bayii. 

Mo dọgbọn boya mo le fi ọrọ da awon okunrin yii duro, titi ti ọrẹ ọkọ mi yoo fi wa mi wa si ita. Sugbon awon okunrin yii ko fun mi laye rara.

Won mu mi wọle sinu ọkọ yii lọwọ kan naa, ọkọ naa si ṣi. Ọkan ninu awọn okunrin naa joko timi lẹyin, mi o si mọ bi mo se fẹ mu ẹrọ ibanisọrọ mi jade. 

Igba to ya ni ẹrọ mi gbọ̀nrìrì mọ mi lara, nitori wi pe mo ti pa orin ori foonu mi. Bi mo se mu foonu mi jade, oruko ọrẹ ọkọ mi lo han loju ago mi. 

Sugbon okunrin to wa lẹgbẹ mi ko fun mi ni anfanni lati gbe ipe kankan, o wi pe ofin ti won fun awon niyen. 


O ni ti ko ba temi lorun, mo ni anfaani lati bọ silẹ ninu mọto awon ki n ma ba temi lọ. Mi o mọ ohun ti mo fe se. Ti mo ba ni ki n sọ ninu ọkọ yii, gbogbo otitọ ti mo fẹ fi han aye jasi pabo. Amọ kini idaniloju wi pe ma ri otito yii gbamu gege bi èrò wa? 

Leyin ti mo ti padanu oluranlowo mi (ọrẹ ọkọ mi). O daju wi pe inu idaamu ni ọrẹ ọkọ mi yoo wa, yoo si ti ma wa mi kiri.

Se ọga yii koni pada ba mi sun nitooto bayii? Tori ti mo ba pada ko fun un, se ko ni mu mi ni tipatipa ti ko si sẹni to le gbami lọwọ rẹ?
Ibo gan-an ni mo mo ti won n gbe mi lọ? Sugbon ohun ti mo tun ro ni wi pe, ko si anfaani lati tun ọgbọn yii da ti mo ba fi le padanu otitọ ti mo fẹ gbamu ni alẹ oni. 

Mo pa èrò mi pọ, mo si pinnu lati tẹle awon okunrin meji yii lo. Okunrin yii beere fun ẹrọ ibanisọrọ mi, mo si mu le e lọwọ. 

Igba to ya ni atẹjisẹ kan wọle si ori ẹrọ mi, okunrin yii ko tilẹ yẹ ẹ wo, o pa foonu mi patapata ni. 

Mo dakẹ mi o wi ohunkohun. Bẹẹ ni ọkọ wa n tesiwaju ninu okunkun birimu ni ale ọjọ naa. Ẹru n bami ninu okan mi, tori mi mo ibi won gbe mi lọ. Sugbon mi o jẹ ko han ninu isesi mi.

Mo se ileri wi pe mi o ni pẹ pada lati se alaye ohun ti oju mi ri nipa ibi ti won gbe mi lọ. Gbogbo ohun to sẹlẹ nibẹ ni ma royin pata. 

Emi ni ti yin ni tooto.
Olabisi K.


Ẹ tẹsiwaju ninu itan igbesi aye Olabisi K NIBI























Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment