Smiley face

Yoruba Dun: Itan igbesi aye Olabisi K (3)



Eyi ni awon esi ati amoran ti awon eniyan fun Olabisi K lori leta re to ko gbeyin. A ko se atunse tabi atunko si awon oro won, bi won se kọ gẹlẹ naa la tun tẹ.   
Yoruba Dun: Itan igbesi aye Olabisi K (3)
Iyanda Adeola Omodele: Afi ki Olorun kio gbani, fi okan oga naa le olorun lowo, mo gbagbo pe pelu olorun ohun gbogbo ni sise.


Oluwabukunmi Best: Kilode ti awon eniyan fi ma n nife si o ru leta bayii,oun to je wipe pelu ibanuje ni onileta fi ko,won o si tun like re,ko da rara.ki omidan na ma gbadura dada ki olorun fowo kan okan oga naa.

Malik Wasiu: Gbo gbogbo oro ti awon eniyan ba eso man ta ara e lopo fun ole je pe ofe dan ewo ni olohun o ni damu re ko se jeje

Mary Olaide Possibility JP: Hun un! Gbogbo imoran awon elegbe mi lo dara. Sugbon awon ibere kan ni emi mimo fi simi lokan lati bere lodo arabinrin wa, nje iwoso re jo ti omo Olorun tabi musulumi ododo? Se iwoso re ko ma polowo oja? Se iwoso re ko ma fi oke oyan sile niwaju oga? Se ki se pe o n sagi lo si iwaju oga? Iru awada wo lo ma nba oga nigba to sese de? Se iwo gan o ti sare koja Eleda nipa wiwa ojurere oga yi boya lodo awon woli tabi alafa? Nje o ni ikora eni ni ijaanu nipa aye re? Dahun awon ibeere yi ninu okan re, ti o ba ti yege, lo ninu adura ojo meta pere pelu pls3 wipe ki Oluwa gbe ayonilenu aye re jinna sio. Ti o ba ti je pe obinrin ni o bi, ko gbodo pari osu yi lodo yin ti emi mimo yo fi si nidi.

Saheed Olayemi: Afommar Oro na so si ni lenun obu iyo si, abi bo lawa ti se eleyi si,se ni ibi ti oro ise ti di oun kan ni ati so wipe ki enikan fi ise le, elomiran ti un wa ise yi fun opolopo odun ti kosi ri.abi a o wa so wipe tori ise ki aye eni eleni kio baje ni,arabinrin elo ni igbagbo ninun olorun kie si gba wipe kosi oun ti olorun ko le se.

Prince Adeolu Akinola Atayese: Ma gba fun weere yen o le kuro nibe fun Tolorun lo ju ati pe omi ti eda ma mu ko le san koja re

Princess Dorcas Babatunde: Un oro sunukun oju sunukun na la kuku fi ma wo.amo sepe awon enibi siwalaye sha amo ki emi to ma da eni eleni lebi ejekin bi arabirin yi lere ibere kan tabi meji tori woni agbejo enikan da agba osika ni.omidan labisi se ki sepe seni eyin na man wo awon aso ti ole mu eniyan kose lo sibi ise,se ki si sepe seleman bere inkan lowo oga yi bi owo tori yoruba bo woni eni toba rin ni bebe idoti ni won man fi egbin kan atiwipe ese eyin nikan ni omidan towa ni ibi ise yin ni.mi orobe, en,kiwa lode tojewipe eyin loko enu iru orobesi,ajepe oriyin beni,toba jepe se ni ema hu iru iwa bayii,egbiyanju lati yiwa pada ki eyin na wawo boya oga yi yio yi iwapada siyin,amo toba jepe eki hu iru iwa bayi amo tojepe oga yin lo kan fe ya agba ya ton sunkun fida omore ajewipe agbare fe te nu.emi iba wa gbayin ni imoran wipe kegba ikiyesara lopolopo ki ema si gba lati fi iyi obirin yi han enitio nife yin tokan fete arare lorun,ewo egbeti ise yin ti sapakan lori oro yio,se eyin gbon bi olorun to tete pese ise fun yini ewo ematori wipe efe jeran kewa mape malu ni buroda,agbedo!!.emase gbarara lati bani ajosepo kakan botiwu omo,koda toba je pe emeta lemarira tele eso di ekan,boba je pe eyin ni esumo ju nibi ise egbiyan ju kie faseyin die,nipa sise eleyi molero wipe tikobariyin mo bi ti tele ko ni fi oju si yin lara mo nipa bayi yiobere sini gbagbe ero okan re buburu,tiko bawa gba gbe ajewipe agbalagba re tin se langbalangba nu ewaje komo wipe won ko yi egba eko,koda ekowe fise re sile kotoleyin kesi jeko mo idi te fi sebe kole bamo wipe isere kole sope kemada de ibi ti olorun ti pese sile fun,oleyi ipinu re pada lojo teba se eleyi kosi beyin amo ti ko ba se ajepe ofe leyin baire ni.paripari gbogbo ekun fun adura ki e si ma pa ofin olorun mo.olorun yio mu yin borio (amin)

Amoke Olushola: mase gba enikeni laye.ki won ma ba fi ogo ree ta ayo.ko si ibikibi ti ole wa ise lo.ti iru nkan bayi ko ni sele.Mo gba ni adura fun e pe ogun ati ipilese ti ko fe ki o ni isimi ki oluwa so won di alailagbara.mase ko adura sile.sora re mase ro ejo oga re fun enikeni ni ibi ti o tin sise.oluwa yio se ona re ni rere o.ire.

Adegboyega Siji: Ti oro ba ri bayii,to awon ojise Olorun lo lati ba o sona.Ti Olorun ba so pe ki o duro,nipa aawe ati adura,waa segun ota re yii.Ti o ba si je pe oga yii ni Olorun fee lo lati mu o kuro nibi ise naa ki o le debi ayo ti Olorun ti pese fun o,ma jiyan.O si le je nipa tire ni oga yii yoo fi yipada tabi ko kan idin ninu iyo.O se pataki lati se iwadii. Iwo naa niilo adura ati aawe.Oluwa yoo segun fun o.

Olukunle Modupeola: Omidan olabisi amoran temi nipe ma fun oga kankan laaye lati ba ojo ola e je, ti oba de le e nibise e sebi ko le e laye wa ri ise mi ti oba ti ni igbagbo.


Ogunlade Oladele Olanike Oluwatoyin: amoran temi niwipe.....ki o tera mo adura nitoriwipe ko si ohun ti adura ko le se...ki o ma se gba fun oga yen lati ba ni asepo nitori pe o le da eto rere ti olorun ni fun duro..nitori naa ki o tera mon adura olorun a si gbo adura re..

Ogunrinola Ahmed Ayinla Medulla: Oma sii se mi lanu pupo wipe iru awon onibi ba yii tun si sekun lori le. Amoran temi sie ni wipe magba ati lajosepo kan kan pelu ee, ki o si fi oro re loo Eledua ki o gbe airoju airaye fun ki ole je ki o raye see tie. Bi owa da e duro wayi, Olohun loni ise, Ohun naa si ni eni ti o n pese ise irorun fun eda. A si ona otun fun e ti o ba da eeja.......


Olalekan Taiwo Omolola :Olorun ni alabo e,i pray dat he wil guide u through

Isola Niyi Nifochrist: sebi ete ni agbara obinrin, o rorun ki o lo ete yii lona ti o ba ofin mu, emi ki ba ni ki o pe si ile re, ki o si wa ero a gbohun sile ki o e bere ere ife a papandodo lojiji ki o bere sini pariwo pelu esun pe o fe fi ipa ba e lopo. Leyin eyi ki o je ko mo nipa mimu eda re fun pelu adehun pe bi ise ba bo lowo re oro yoo di ti ile ejo

Engr Hammed Ibrahim: Imoran temi ni ipe,ki omidan olabisi kun fun adura,ki o ma se gbagbe pe olorun adake dajo u n be loke to n wo awa eda adamo,e ma ba igbesi aye yin je nitori oga kan amo olorun oba to pese ise yi,yo pese ise miiran tan ba da yin duro,o ma se ooo

Engr Hammed Ibrahim: @ishola Niyi P,iru ogbon ba yen ko le sise,nitori pe eni to ba juni lo le juni nu.

Isola Niyi Nifochrist @hammed ni ile j k, koni f ypr ara r bo ti wu ki o m adaj to ko ni f ki oruk oun baj

Olutoyin Oyedokun-Adeleye: Oro yi lagbara o. Sugbon ko si ohun ti adura se ti. Tera mo adura ni gbigba, ki o si ni igbabo pe Olorun yio ba okan oga re pade. Ti ise yi ba wa bo lowo re nipase oga yi, Olorun yio fun o ni omiran ti o tun dara ju yi lo.

Mojeed Ademola: oloribu loga yen. Se awon eniyan bayen siku laye sa. Omidan maje ki o bae laye jee oo. Mo fi olorun be oo Magba fun oo. OLORUN ako e ma se oo. Amen

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment