Smiley face

Yoruba Dun: Itan igbesi aye Olabisi K (6)



#AyeOlabisiK6
Ọdaju laye, ika leniyan
Yoruba Dun: Itan igbesi aye Olabisi K (6)
Lẹyin ti mo ti ko awon iwe ọwọ mi silẹ tan, ẹni ti won ran si mi ti lo jisẹ loke. Lọwọ kan laago dun kan mi lara wi pe ki n maa bọ loke.


Nigba ti mo doke, oga yii beere faili kan lọwọ mi. Eleyii ti mo salaye wi pe mo ti gbe fun un saaju ọjọ naa. Ko sọrọ le ohun ti mo wi. O siju womi tika-tẹgbin. O ni ki n maa lọ.

Emi si jade ni ofiisi re. Mo gba ofiise accountant lọ. Nigbati mo de ibe, accountant ni won ni ki oun ma fun mi ni nnkankan mọ. Mo pose saarasa mọ ọ lara. A n roju jẹkọ ọbun, obun tun dakọ ẹ kere. Mo binu jade, mo gbe baagi mi mo si n lọ.

Igba ti mo de ẹnu geeti ni isalẹ, ni baba gateman tun wi pe ọga ti pe wi pe won ko gbọdọ jẹ ki n jade.

Mo beere ohun to de, baba gateman ò fun mi lesi ọrọ mi pada. Mo gun oke pada pẹlu ibinu. Kete ti mo goke ni awon olopaa ba de ba mi. Oga mi na ọwọ si mi wi pe ẹni naa re. “Kini mo se?” ni ohun to kọkọ jade lẹnu mi.

Awon olopaa ni mo ni anfaani lati ma wi ohunkohun, tori ohun ti mo ba wi le jẹ atako fun mi ni ile ẹjọ. Mo bẹrẹ si gbe oga mi yii sepe mo sin bi leere oun timo se fun gan-an. Pelu ariwo yii ni awon olopaa mu mi lo si agọ won ni osan ọjọ naa.

Kini idi abajo ti oga mi fifi olopaa mu mi? Iru irọ wo gan-an lo pa mo mi? Kini ohun to sele nigba ti mo de ago olopaa? Ibo loro mi ja si? Ipo wo ni iyami wa nigba ti o gbo isele yii. Gbogbo ohun to sele pata ni maa royin. 

Emi ni ti yin ni tooto. 
Olabisi K.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment