#AyeOlabisiK8
Yoruba Dun: Itan igbesi aye Olabisi K (8) |
Si Olootu Yoruba Dun,
Mo ro wi pe ẹ
si n ba mi fọkan ba lẹta
mi lọ. O wu mi ki n ti pada fun yin ni labaare lẹkunrẹrẹ.
Amọ, ẹni
gbodo mi lọrọ
mi. Iduro ko si, ibẹrẹ
ko si mọ.
Ara o rokun
ara o radiyẹ. A fi aanu Eledumare nikan ni igbẹkẹlẹ
mi.
Ìgbà ti awọn
agbofinro mu mi de agọ wọn.
Won fi ye mi wi pe mo gbé faili isẹ
ti o to ọgọta
miliọnu (60m) pamọ
lati fi da ile isẹ mi
lóró latari ikorira ọga tuntun ti ko faye gba
imẹlẹ,
aise olooto si ile isẹ ati awon iwa to sun mọọ.
Eleyii ti won kofiri wi pe o kun ọwọ
mi.
Se ẹ ko
gbagbe wi pe ile isẹ agbasẹ
se ni mo ti n sisẹ. Awọn ọlọpaa
ni ọga mi se akiyesi wi pe ọta
ile isẹ ni mi. O ni emi ti lọ lẹdi
apopọ pẹlu
awon orogun ile ise awọn.
O ni aimoye asiri ni emi n
lọ tu sita, eyi lo si fa ti ile isẹ
yii ko fi risẹ gba mọ
bi ti tẹlẹ.
Ti ina rẹ si n jo ajo rẹyin.
Won ni ti isẹ kan ba ti yọju,
ko to tẹ awọn
lọwọ
lemi o ti lọ ro fun awọn
orogun awọn.
Awọn
olọpaa ni ki n se akọsilẹ
ohun ti mo mọ nipa ọrọ
yii. Kini mo fẹ kọ gan-an?
Won purọ mọ
mi pe mo su mi o nudi, eniyan meloo ni mo fẹ
sidi han pe irọ ni won pa mọ
mi.
Talo fẹ
gba mi gbọ ti mọ
ba sọ iru iwa buruku ti ọga
mi yii n wu? Awon ọlọpaa
da mi duru si ẹyin ganta. Ibẹ
ni mo sun mọjumọ
ninu ẹfọn
ati otutu. Itọ ẹnu
mi ti gbẹ furufuru bẹẹ
nnkankan ko wu mi jẹ.
Iya mi wa ba mi nigba ti
ilẹ su pẹlu ọkọ
afẹsọna
mi. Won ko ri ọrọ
naa yanju ni alẹ ọjọ
yii. Mo sun ẹyin ganta ti ilẹ
fi mọ.
Ọga
buruku yii ti kọ lẹta
si olu ile isẹ wa l’Abuja wi pe ohun ti ri ọdalẹ
to n ba ile isẹ awon jẹ.
Bẹẹ ile isẹ
yii setan lati ba mi sẹjọ
ti mo ba kọ ati gbe faili yi silẹ.
Ọrọ
to wa nilẹ ti wa rekọja
tọga mi nikan. O ti di emi ati ile ise wa
lapapọ. Mo sukun ni alẹ
ojọ yii, oju mi wu kongbakongba.
O digba kan naa.
Emi ni tiyin ni tootọ,
Omidan Olabisi K.
0 comments:
Post a Comment