Smiley face

Agbeyewo ojulowo ise iroyin to pegede


Adewale Dada Thegood

Akurẹtẹ ti deba isẹ iroyin eleyii to mu pupo ninu awon koko ti ise iroyin dálé di ohun igbagbe. 

Eleyii si sẹlẹ latari imẹlẹ awon oniroyin, ainimọ to kun nipa ohun ti ise iroyin dale ati iwa ibajẹ jegudujera to je orisa kan pataki ti gbogbo wa n bo ni ile Adulawo.

E je ka wo pataki ise Iroyin:

Gege bi Alufa Femi Emmanuel ti ijo Living Springs Chapel se sọ,
“Nikete ti eda eniyan ba ti duro lati maa wa imo tuntun, igba naa ni irufe eniyan bee ti bere si ni dipẹta (ki nnkan bere si ni bajẹ)”.

Ko si iye imọ ti eniyan le ni lagbari, ti ko ba wa imo tuntun mọọ ko le tesiwaju. Idi niyi ti awon Yoruba fi ni aa pe gbon ni enikan ki i pe gọ. Ati wi pe bi oni se ri ọla ko ri bẹẹ lo mu baba alawo maa difa ojoojumo.

Ise Iroyin je ohun ti n se afikun tabi atunse imọ, yala nigba ti awon eniyan awujọ n kọ ẹkọ lọwọ tabi lẹyin ẹko won ni ile iwe. Ise Iroyin je agbara tabi igi leyin ọgba ti yoo maa gbe awon eniyan ro ninu imọ ati iriri ọgbọn to n lọ layika won leyin ẹkọ ile iwe onisabuke tabi ikose-ọwọ.

Gege bi apeere, aimoye awon ise iwadii ọgbọn ni awon onise alakada ti se seyin eleyii to ti duro gege bi imo fun igba pipe. 

Sugbon bi ọjọ se n gori ọjọ ni isẹlẹ tuntun un sẹlẹ lagbaye eleyii to n so pupo awon imo bee di ohun ti o wulo mọ. 

Akitiyan awon oniroyin si maa mu awon onisẹ alakada jigiri lati lo tun Ifa won da leyin abajade ise iwadii awon oniroyin nipa isẹlẹ tuntun to so ogbon ana di omugo oni. Lọpọ igba, awon onise iroyin yoo ti pari isẹ ko to tẹ awon onise alakada lowo nitori wi pe oju won tole-toko.

Gege bi apeere, ka so wi pe orisii kokoro kan ti enikankan ko mo ri tele ti bere si ni yo awon agbe lenu eleyii to n se akoba fun ere oko won ni awon ilu okeere kan, ka so wi pe China. Eleyii ti orisii kokoro naa ko ti di mimo fun awon onimo onise alakada ni ilu mii. Akitiyan ati ilakaka ise iwadii awon oniroyin le je ka mo ohun to sokunfa kokoro buruku naa ati ona abayo eleyii ti o pada jasi iroyin ko to wa di wi pe awon kan yoo tun bere si ni gbeyewo gege bi ise iwadii tuntun ni ilu mii fun aridaju imo ati itesiwaju ogbon tuntun.


Alaye mi ko da lori ariyanjiyan, koko oro mi ko si da lori wi pe Ise Iroyin se pataki ju imo nipa Eto Ogbin lo gege bi Ibrahim se fi ye mi. Ohun ti mi o ni anfaani lati so fun Ibrahim ni pataki ati iwulo ise iroyin lawujo ati bi ise iroyin se jinle to.


Opolopo kudiekudie lo ti de ba ise iroyin ni ile Adulawo latari imele awon oniroyin, aini imo to kun nipa ohun ti ise iroyin dale ati iwa jegudujera awon eniyan dudu. Eleyii si mu ki awon oniroyin so agbara won nu lati igba pipe seyin. 


Kini Ise Iroyin Gan-an?

Mo ti se iwadii lorisirisi lati mo ero awon ojogbon ati awon onilaakaye nipa ojulowo ise iroyin ati ohun ti ise iroyin dale. Gege bi akosile American Press Instistute, awon gba wi pe ise iroyin dale sise akojopo awon isele fun ikede.
“Journalism is the activity of gathering, assessing, creating, and presenting news and information. It is also the product of these activities.”

Omowe Anthony Curtis lati Ifafiti Carolina ni eka ti won ti n ko nipa Igbohunsafefe ati Ise Iroyin naa fi idi alaye tie naa mule:
“Journalism is the practice of investigating and reporting events, issues and trend to the mass audiences of print, broadcast and online media such as newspaper, magazines and books radio and television stations and networks, and blogs and social and mobile media.”

Robert Niles ti gba orisirisi ami eye gege bi oniroyin ori ero ayelukara, mo si ro wi pe oro to ba so ko ye ki eniyan le ko danu rara nitori ojo tipe ti omo obo ti fi ori igi sele. Ohun ti Baba naa wi ni yii:
“Journalism is form of writing that tells people about things that really happened, but that they might not have known about already. People who write journalism are called “journalist”. They might work at newspapers, magazines, websites or TV or radio stations.” 

Bi o tile je wi pe pupo ninu awon alaye won lo kesejari ti awon eniyan si tewo gba nipa ohun ti ise iroyin dale lori. Sugbon ko si eyi to ba ero mi lo. Agbekale Dr Anthony Curtis yaayi pupo, sugbon alaye naa ko kun to. Ma gbiyanju ki n so ohun ti ise iroyin tunmo si gege bi ero mi ati iriri mi ki n to wako alaye mi gunle patapata.  
  
Sugbon kii eegun mi to ma jo siwaju, e je n duro nibi lati se afihan awon Oniroyin ti won ti doosa ajiki nipase ojulowo ise iroyin to kunfofo bi ataare to n ti owo won jade. Irufe awon eniyan yii ti kuro ni ipele oniroyin lasan, won ti di onwoye agbaye nipa igbe aye eda lawujo. 
Oprah Winfrey
Yato si ise iwadii, agbekale alaye to se koko si igbe aye eda eniyan, iroyin irinkerindo nipa awon orileede agbaye, lara ohun to mu eto Oprah Winfrey di gbajugbaja kaakiri agbaye ko tayo orisii ogbon ayinike ise iroyin igbohun safefe to n lo. Eleyii to je wi pe pupo awon onworan re kii le yira pada titi arabirin naa yoo fi pari eto re lori afefe. Orisii ogbon yii ni awon oluko wa n pe ni ikonilokanro (suspense) ninu litireso.

Kosi bi babalawo se lekenka to nibikibi lagbaye, Araba Ifayemi Eleebubon loga nla, to ba jo bi iro eni e ba ri ke e bi. Ojogbon Wande Abimbola si ni Oosa rabata ti won fi ori bale fun to ba dibi ojulowo imo nipa orunmila baba Ifa. Oniroyin le ni oruko nla pelu okiki, sugbon abaje  iwadii fi ye wa wi pe Larry King ni ilu Amerika ni sorosoro ori afefe to laponle julo nigbogbo orileede agbaye. 

Larry King Live
Sugbon ninu okan mi, mo ti pinnu pe lojo kan maa foju kan Christiane Amanpour. Maa si fila fun ori ade, ma si beri fun akoni obirin bi okunrin ninu ise iroyin to danto. E maa fi oniroyin we oniroyin, oloju akosemose to mose akin to yanranti bi Amanpoul. Oloju onisegun to le fe abirun niyawo. Oluko ti o ko akurari ni takada loju lasan o wopo. E maa je n tan yin, oniroyin kan ju oniroyin kan lo. Oga ni kaun lawujo okuta. Oga niyo lawujo erupe. Ojo ti Yasser Arafat, Bashorun Gaa ilu Palestine gbenakari, Christiane Amanpour sokale. E ma f’amala dudu we iyan Ekiti laelae. Oloju oniroyin to le soro dasaka loju ogun ida ati bajinatu. Eyi to lagbekale ko lakinkanju bee akinkanju nise iroyin to fakiki pelu agbekale to kun fun ogbon ti n tu gbogbo alaye to ta koko.
Christiane Amanpour CNN
Ki ni ohun pataki to so awon oniroyin doosa ajiki? Abi ki n so wi pe ki lo mu awon oniroyin kan pegede ju awon oniroyin mii lo?

Lakoko na, ise iroyin rekoja ikede gege bi ero opolopo awon eniyan. Bi awon oniroyin tile n kede isele awujo si eti ara ilu, a je wi pe ikede isele je bi okan ninu ogorun ninu ohun ti ise iroyin gun le ni.

E je ka se agbeyewo alaye kekere yii:
Pelu anfaani awon ero iwiregbe to wa lori ayelukara bi Facebook, Twitter, Instagram, BBM ati bee bee lo, nibi ti awon eniyan orisirisi ti maa n kede isele ayika won, isele inu ile won, awon mii tile maa n kede awon isele ti n sele ninu igbe aye won ati oun ti won ro lokan. Ti ise iroyin ba je ikede isele, nje a le gba wi pe oniroyin ni gbogbo awon eniyan ti a se apeere won soke yii je?

Kini Ise Iroyin sise je gan-an?
Ise Iroyin ni akojopo eroja ti ko leja-n-bakan ninu nipase itopinpin ati iwadii ijinle eleyii to da lori isele awujo lati fi kede isele, se alaye ohun to ruju, idanileko, ikilo, atunse, tabi idanilaraya fun awon eniyan awujo laikuna ninu ofin igbekale ise iroyin sise.

Niwon igba ti oniroyin ko ba ti ni oye nipa ohun ti ise iroyin dale, ni o soro fun iru oniroyin bee lati kogo ja.
 Yato si ojulowo imo nipa ise iroyin tabi igbohunsafefe;

  • Oniroyin gbodo ni oye nipa asa ati ise awon eniyan awujo ti won n tewo gba abajade ise oniroyin tabi ti koko iroyin naa dale lori.
  • Oniroyin gbodo mo nipa awon eniyan awujo; gbedeke imo ori won, ero okan tabi irori won, ohun ti won n reti lati odo oniroyin, iha to seese ki won ko si orisii abajade tabi agbekale iroyin kan nipato.
  • Oniroyin gbodo mo nipa igba ati akoko to n lo lowo eleyii ni yoo ran-an lowo lati le se agbekale ise iroyin ni ona ti o fi ba igba mu.
  • Yato si wi pe oniroyin n sise pelu awujo, oniroyin tun sise ‘laaarin’ awujo. Eyi lo fi je dandan gbon fun ojulowo oniroyin lati ni imo gbogboogbo nipa ohun to gbe awujo ro  bi eto eko, eto oro aje, ere idaraya, oselu, isejoba, amuludun, eto ilera, eto isuna owo, eto ogbin, ibasepo awujo pelu orileede agbaye, ofin ati eto idajo abbl.

Ti mo ba ni ki n maa ka awon abuda ojulowo oniroyin, oseese ko gba mi ni opolopo akoko eleyii ti gbogbo re si se koko. Ise iroyin jin pupo bee lo si fe feregede bi owo aso.  Eyi lo fa ti awon oniroyin fi yan abala ise iroyin kan nipato fun ise iwadii to jinle. Sugbon fun ojulowo oniroyin, dandan lo je lati ni gbogbo abuda ise oniroyin nitori gbogbo re wonu ara won ni.
Yato si awon sawo-sogberi oniroyin, a wa le gba wi pe asaaju (leader) to pegede ni ojulowo oniroyin to gbamuse lawujo igbe aye awon eniyan.

Eni to feebo nile ana dandan ni ko tu u.

Awon wo ni Sawo-Sogberi?
Gege bi Ojogbon Akinwumi Isola se so ninu alaye re. Kofeso so wi pe awon Sawo-Sogberi ni orisi awon eniyan kan ti won maa n sebi awo loju awon eniyan ti ko mo ohunkohun sugbon lojo ti won ba pade ojulowo awo gidi (akosemose), iru won yoo pada di ogberi. E yi tun mo si wi pe ayederu ni won.

E ri wi pe mo se apeere oniroyin gege bi asaaju tabi eni to le di ipo asaaju mu. A le gba wi pe bee naa lori nipase Imo, Iriri igbe aye awon eniyan ati ibasepo oniroyin pelu awon eniyan awujo lenu ise won. 

Tani asaaju?
Asaaju kii se eniyan ti n lo niwaju ti awon eniyan to ku n tele leyin.
Asaaju kii se eniyan to wa ni ipo agbara lati dari awon eniyan to ku leyin.
Asaaju kii se orisii eniyan ti awon kan n bo bi oosa.

Taa wa ni asaaju?
  • Asaaju ni eniyan to n lo niwaju lati pese ona fun awon to n bo leyin lati ri ona to dara gba koja.
  • Asaaju ni eni to n tiraka lati mo ohun ti opolopo awon eniyan ko mo pelu ero ati fi orisii imo bee se iranlowo fun awujo.
  • Asaaju ni eni to mo ona lati je ki ifokanbale pada si aarin ilu ni akoko ti awujo wa ninu hilahilo tabi aibale okan.
  • Asaaju ni eni to n lakaka lati je ki awon eniyan awujo bo sinu ominira kuro ninu iponju ati ipayinkeke.
  • Asaaju ni akinkanju to duro lori ododo ati igbagbo nipa ojo ola rere awon eniyan.
  • Asaaju je eni ti ki beru ohunkohun; awon kan so wi pe ohun ni won pe ni igboya.
  • Asaaju ni eni o n lo anfaani to ni, yala dukia tabi imo fun idagbasoke awujo tabi ilu re.
  • Asaaju ni eni to fi ara re sile lati je ohùn fun opolopo ti won ko lenu lati soro lawujo.
Awon nnkan ti awon oniroyin agbaye bi Larry King, Opral Winfrey ati Christianah Ammanpol mu mo ise opolo ni yii ti won fi di eni aponle ti gbogbo awon alagbara aye fi n ye won wo bi ifa to ba dibi oro iselu  tabi eto ilu.  

O seese ko je wi pe awon nnkan yii ni awon Ojogbon ro papo nipa akitiyan Adewale Dada lawujo ti won fi fi oye Dokita da lola. Eyi si wa lara nnkan ti itan ko ni gbagba laelae ninu ise iroyin igbohunsafefe ile Naijeria ati ile adulawo lapapo.
Dr. Adewale Dada TheGood
  • Igba ti ilu wa ninu rukerudo, Adewale Dada dide lati ponlogo alaafia.
  • Igba ti awon omo ale tabuku ile Naijeria, Adewale Dada dide lati maa bu ola fun un.
  • Igba ti awon eniyan so ireti nu, Adewale Dada se afihan agbara igbagbo ati ireti.
  • Igba ti awon eniyan karibonu, Adewale Dada lo ebun re toni lati ko ibanuje awon eniyan danu sinu okun pupa.
  • Igba ti awon ojelu te eto omoniyan mole, Adewale Dada duro lori ododo lai foya.
  • Igba ti awon odo ile yii se bi o ti tan, Adewale Dada se idasile The Good Intiative lati ran awon alaini lowo.
Akinkanju, olotito, asaaju rere, ore mekunnu ni Adewale Alao omo Dada je.

Eyi ni die lara apileko ti awon  Ojongba ka si eti gbogbo aye ko to di wi pe won wo aso oye fun Wale Dada, leyin eyi ni won gbe Sabuke oye Dokita le lowo ni ilu Ibadan. Gongo so!

“Akosile isele tuntun ti wonu iwe itan laaarin awon ojogbon onise alakada lonii. Ohun gbogbo ni eniyan le kowo ra, eniyan ko le fi owo ra oye Dokita iru eyi. Awon eniyan awujo dabi osere ori itage loju ti wa, a si n se akiyesi ipa ati akitiyan enikookan nipa idagbasoke awujo wa. A n se eyi lati se koriya, idalola ati imoore.”
Adewale Dada Thegood
Ise iroyin je ise akinkanju ati ise ilu- ifi ara eni jin fun ise ilu. Oniroyin to ba ni oye nipa ohun ti ise iroyin gunle, to si tele awon ilana to ro mo o nipa nini awon abuda to ye ki ojulowo oniroyin ni, a le pe iru oniroyin bee ni asaaju gidi lawujo.

Ibi ti maa ti duro ni yii, mo dupe fun ifarabale yin lati ka alaye mi.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment