Ní ilè Yorùbá, a kìí kàn án sàdédé pe ènìyàn ní omolúàbí.
Adé orí la fi n moba,ìlèkè la fi n mo ìjòyè, ìpèlé tòhun gèlè tó se régí la fi n mo ìyálóde yàtò láwùjo obìnrin, eyí ni wí pé ó ní àwòmó pàtàkì tí a máa n wò lára ènìyàn kí á tó lè pèé ní omolúàbí.
Taa ni Omolúàbí? Omolúàbí ni eni tí ó kó gbogbo ìwà rere pò, tí ó sì jé eni tí egbé, ogbà àti àwon àgbà kà sí ojúlówó ènìyàn.
Àwon àgbà mìíràn tú òrò yìí sí. OMO TÍ NÚÀ BÍ pèlú àlàyé wí pé ìwà rere Núà inú bíbélì ni kò jé kí ó bá èkún omi lo, nítorí náà ìran omo Núà níí hu ìwà rere.
Àwon àgbà Òpìtàn kan tún sàlàyé wí pé àgékúrú OMO TÍ OLÚ-ÌWÀ BÍ ni Omolúàbí.
Wón fi ìdí èro won múlè nípa sísàlàyé pé Olú-ìwà ni odù tí ó dá ìwà, lára àwon èbùn tí Olódùmarè fún un ni ìwà rere, ìtélórùn,sùúrù àti ìfé (tí ó jé àkójá òfin)
Bí a bá wá se àwòfín ìtumò métèèta, a ó rí i wí pé orí ìwà rere náà ni ó dálé.
Yàtò sí ìwà rere,ohùn rere ní n be lénu Omolúàbí, nítorí pé ó mò pé òrò tí ènìyàn bá so lénu ló n fihàn bí okàn àti inú rè ti rí.
Kàkà kí Omolúàbí sòrò búburú. lénu,ó máa dáké ni.
ÀMÚYE OMOLÚÀBÍ
Àwon àgbá bò wón ní; "ilé làá wò ká tó somo lórúko, béè ònà tómo bá bá wáyé latóka orúko rè." Kí á tó lè pe ènìyàn ní Omolúàbí, irúfé eni béè gbódò ní àwon àmúye wònyí;
(1) Ó MÁA N PA ÒFIN MÓ: Omolúàbí kìí tàpá sí òfin agbo ilé, àdúgbò, ìlú àti ti orílè-èdè.
(2) Ó MÁA N KÍ NI PÈLÚ ÌYÉSÍ: Tàárò tòsán,tìròlé málé ni omolúàbí fi máa n kí ni pèlú òwò àti íyésí.
Omolúàbí kìí hùwà ìjoraeni lójú nítorí náà kìí fojú kéré enikéni.
(3) Ó MÁA N NÍ ÌBÈRÙ LÓKÀN: Omolúàbí a máa ní ìbèrù Olórun lókàn nínú gbogbo ohun gbogbo tí ó bá n se, bákan náà ni ó tún máa n fi òwò àti àpónlé tí ó ye fún àwon àgbà.
(4) KÌÍ HÙWÀ ÀGÀBÀGEBÈ: Béèni omolúàbí kìí lábùlà béèni ló máa n jé ní gbogbo ìgbà, ojú kan báyìí ni àdá Omolúàbí máa n ní.
(5) Ó MÁA N SE ÌRÀNLÓWÓ: Omolúàbí kìí ní ìmotara eni nìkan, ó máa n ka ìsòro àwon ènìyàn àyíká rè sí tara rè, fún
ìdí èyí kìí yo nínú ìsubú elòmìíran dípò ayò, ìrànlówó ni ó máa n se fún eni tí ó ní ìsòro.
ìdí èyí kìí yo nínú ìsubú elòmìíran dípò ayò, ìrànlówó ni ó máa n se fún eni tí ó ní ìsòro.
Pèlú ìwònba àlàyé tí a ti se yìí, ènìyàn mélòó ni òsùnwon rè gbéwòn láti máa pè ní Omolúàbí?
Orisun: Olùkó Èdè àti Àsà Yorùbá Arb (2016)
0 comments:
Post a Comment