Smiley face

Ìlú wo ni ilu olókè púpo nile Yoruba? Asiri idanwo ni yii

Ilu pò ní lórílè-èdè yìí ní tòótó,
Eye bí òkín ìlú mi sòwón.

Ojú tí ó rí òpò omi láì mo òkun,
Ojú òhun ò tíì rí nnkan kan.

Bí ènìyàn bá jé gbajúmò,
Tí wón n pe Olúwarè ní Ìlúmòóká,
Àmó tí Onítòun kò dé ilè abínibí mi,
Eni náà ò tíì mo ibì kankan.

Bí a bá yo ti àsorégèé kúrò,
Ilè tí ó kún fún wàrà àti oyin ni a gbé bí mi.

Akínkanjú níí darí wa,
Ògbónu-gbóyà sì ni wón pèlú,
Ogbón wa ò gbòn dànù,
Ète kankan kìí re wá bété.

Ìlú olókè púpo ni ìlú abínibí mi;
Òke Fòkò,Òkè Ààre,Òke Bólà, Òkè Àdó,
Òkè Adú, Òke Dàda, Òke Sápátì,
Òkè Páàdì àti Òkè Màpó ni àwon òkè tí ó sisé ààbò fún àwon akoni wa nígbà tí Ogun gbóná janjan bí èko àsèsèpò.

Òsé méjì ni odù tí a fi te ìlú abínibí mi dó.

NJE ÈYIN MO ÌLÚ ABÍNIBÍ MI BÍ?


Orisun: Olùkó Èdè àti Àsà Yorùbá Arb
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment