Niwon igba to je wi pe gbogbo eni ti n korin ko ni won korin gidi, bakan naa, a le gba wi pe gbogbo onise tiata ko nise opolo won kun fofo bi ataare.
Sugbon sa, ko si bi won se fe ka awon agbaoje onise tiata ti won ko ni daruko Afeez Eniola.
Gege bi osere, o je enikan to ma n gbe eda itan (Character) re wo bi ewu patapata. Eleyii si je okan pataki ti o fi maa n wu awon ololufee re. Bi o ba se odaju eniyan ninu sinima, odaju ni eniyan yoo pe loju aye. Bo si se eda itan eniyan rere, oju alaanu ni gbogbo eniyan yoo fi ma wo o.
Sugbon kini tuntun nipa Afeez Eniola?
Afeez Eniola yoo wa lara awon irawo ti yoo pejupese sibi ayeye ifilole awo orin tuntun Olajire Twins ti yoo waye ni ojo kesan-an osu kokanla odun (11-09-2016) yii ninu gbongan nla Ile Orin Yinka Ayefele to wa niluu Ibadan. Yato si ifilole awo orin ti won pe akole re ni "DIVINE UPLIFTMENT", ojo yii tun ni ayeye ojo ibi awon ibeji Olajire.
E je ka pade nibe!
0 comments:
Post a Comment