Smiley face

Omo Fela fi abuku kan Ooni Enitan Adeyeye Ogunwusi

Seun Kuti
Seun Kuti, okan ninu awon omo oloogbe Fela Anikulapo-kuti ti naka aleebu si Ooni Ogunwusi nipa bi oba alaso funfun naa se ni Jesu Olugbala ni baba oun.

Seun ni oju gba oun ti fun Ooni pe, bo se ni Jesu ni baba oun. Koda, omokunrin naa se sio sio sio leemeta fun Ojaja II.

O ni gbogbo ohun etutu ti oba je ko to gori oye nko? Bakan lo tun bere wi pe, die lara ara eran oba to gbese to towo gege bi ara eto ifinijoba nko?

"Oba naa ko ti le mo ipo to dimu ati awon nnkan to romo ipo oba to je. To ba mo ni, ko ni ma so ohun ti n so lenu. O ju gbami ti fun oba naa pupo" Seun Kuti lo so eleyii lori Telifisan Sahara

Odun 1983 ni won bi Seun Kuti siluu Eko. Ise orin kiko nise re bi ti baba re Fela. Esin abalaye ti Fela fi le won lowo naa ni won si n se.

Awon ohun ti baba re n se loun naa n se. O le korin, o le jo ijo-fegbe jo, o le fon feere bakan lo si man fa ogidi igbo to ki bi ti Baba 70.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment