Aare ana, Goodluck Jonathan se abewo si Aare Muhammadu Buhari lonii ojo keta osu kejo odun(03/08/16), bakan naa ni won se ipade idakonkon.
Niwon igba to je wi pe won ko se ipade niseju enikeni, inu yewu ninu loun-loun ni awon mejeeji wo lo lati so awon oro won.
Buhari bu opolopo ola fun aare ana, leyin ipada won, o ri daju wi oun paa GEJ lese da titi won fi deta gbangba nibi tawon oniroyin ti gbe surubo oga Jona bi igba teesin ba surubo imi omode.
Opolopo awon eniyan ni won ti n mefo nipa ohun to seese ki won ba ara awon so.
Awon kan ni Buhari lo ranse pe GEJ nigba ti awon kan wi pe, GEJ lo kowe si Buhari pe oro pataki wa.
Oro wo ni won jo so? O le je nipa jegudujera owo to sonu. O sile je wi pe GEJ wa oju ire Buhari wa lori awon oro kan.
Sugbon ohun to daju ni wi pe, erin ni awon mejeeji rin jade. Won doweke, won si n bohin kee bi eni to ri "Credit Alert" lori foonu re .
Ti PMB ba soro kekere ni kelekele, GEJ yoo rerin bi eni ti won fi iye adiye rin leti winiwini.
Ti GEJ naa ba soro, PMB yoo si gbogbo ehin soke bi gambari ti won fun ni gooro je.
0 comments:
Post a Comment