E ku asiko eyin eniyan mi, o ti wa ninu asa ati ise mi lati se igbelaruge fun awon ologbon odo tabi awon eniyan ti won gbiyanju lati se afihan ebun won lawujo.
Leyin itakuroso die to waye laaarin emi ati Ogbeni Oladeji Kehinde, omo akekoo AAUA to wa nipinle Ondo, o pinnu lati fi apileko re sowo simi. Ogbeni naa ko jamikule leyin ti owo mi te apileko re to fi sowo simi nipa sinima agbalewo Yoruba, eleyii to kun fun opolopo laakaye.
O se afihan opolopo arojinle ogbon pelu agbekale Yoruba to yanranti. O pe akiyesi awon eniyan si ibere ise fiimu ati ibi ti ise naa deduro. Bakannaa ni ko sai naka abuku si kudiekudie simina ode oni ati akoba ti n se fun awujo wa.
Boya ki n se gafara die na nibi, nigba ti n ma fayin le Ogbeni Oladeji Kehinde lowo.
Ogbeni Oladeji o ti ya o ...
Eni ran ofofo nise to ni ko je daadaa egbàá ti yoo san ni o ni, eni bi alápepe leere oro to ni àlàyé o kun to; asodun lo ku tonitohun n wa.
Sinima-Àgbéléwo ti de ile yi ojo ti pe, èdòkì imo ti n fi n koni ni o je ki awon otokulu o ka kuro nile.
Hubert Ogunde se gudugudu meje ohun yaayaa mefa ninu sinima alágbàá, o ni ohun ti iShow Pepe ri ko to fori ró rukerudo iberepepe to doju ko atiwaye ere agbelewo.
Eyi o wu a wi, sinima Yoruba ti fese mule nile yii na, eni ti o dun mo ninu lo mo.
Ohun ta o mo la o mo, ohun to ba daniloju baa ba fogun e gbari ko leewo.
Igbelaruge asa Yoruba lo gun awon tisaaju ni kese inu ti won fi n se ere, itankale isokan omo kootu lo sekeji re. Gbogbo eni ba wo SAWORO-IDE yoo ranti ohun a n wi OLEKU paapaa yoo ran ni leti asa.
Omi inu n ko mi , bee laya n fo mi lori bi sinima agbéléwo Yoruba ti se da loni. Mo sun mi o le sun mo wo orún kò ko gbe mi lo. Bi asa Yoruba ti se n wookun lo gbemi lorun lo ainaani isese ni o je sasun piye.
Ohun Ogunde ni ko ma kin Iran Yoruba leyin ti fegun sowo, ere itage ti Duro Ladipo ni ko fe wa loju ti wa kata senu.
Iran wa ìí rinhoho; Asa Oyinbo ni. Awon sinima to n Jade laye ode oni ti n fowo ro asa wa danu a si jokoo a n woran. Yoruba o dun lenu awon onsere mo amulumala ede lo ku tiwon n so.
Gbogbo ohun to je ewa ati iyi odobinrin laye atijo ni fiimu ode oni ti n gba danu ninu ka woso to sira sile, kobinrin woso ti o bokun.
Lojoun ana, awon agba osere bi Ade Love a maa fi ere won kilo iwa ibaje, won a ma fi safihan awokose rere, apeere leree TOLUWANILE.
Lonii, kafari apakan dapakan lo ku ti awon onisinima n se, olaju paapaa ti n so awon ohun èkò di ohun ègbà a o wa moyato ninu Geesi ati Yoruba.
Se ti ka lo mo ara eni bi ejò lómógi ni ka so ni tabi ti ifenukenu, ifetekete , ìgbéñkanluñkan to gogo ninu Sinima-Àgbéléwo Yoruba ni ka menuba. Gbogbo re naa ni a n pe ni ere lasan.
Yoruba kii wuwa idoti ni koro, eni ba se ni gbangba yoo kan koja abuku. Iwa idoti lo kun fiimu ode oni, kowo sa ti wole ni ohun to je won logun ni ti won.
Ka fe wo sinima nile ka le omokekere jina ki oju majesin o ma ba a ribi, ka le tegbon-taburo siyara komo iya meji o ma baa rewele ninu fiimu. Omode o rekoo rere ko mo ninu Sinima-Àgbéléwo Yoruba, o se.
Looto lododo awon osere to moyì asa si n be, awon onkotan ti o koyan isese kere naa si wa pelu amo won o to nnkan. Sinima iru won paapaa ki i ta boroboro, ere abule ni won n pe ere iru won.
Ere onihoho po bi bebesua, sinima gbébongbébon po ju iyanran. Omoge to ba sira sile ni i laamilaaka lode oni, eléhàá Nollywood o ni rise gba bòrò.
N o pe olaju o dara, n o si pe o leewo ka da aso igba fungba amo kama ríyàálé ka kòyàwó, ka ma folaju gbagbe orisun wa.
Yoruba ronu. Ki gbogbo oludari fiimu o sasaro, ka sun ka ronu bi awon ti tisaaju se bere ka ye toju ile mole.
----------------------------------------------------------------------
Too, oro leti gbo un lati owo Oladeji O. Kehinde. Ohun to koju si enikan, eyin lo ko si elomii. Kini ero ti yin?
Leyin itakuroso die to waye laaarin emi ati Ogbeni Oladeji Kehinde, omo akekoo AAUA to wa nipinle Ondo, o pinnu lati fi apileko re sowo simi. Ogbeni naa ko jamikule leyin ti owo mi te apileko re to fi sowo simi nipa sinima agbalewo Yoruba, eleyii to kun fun opolopo laakaye.
O se afihan opolopo arojinle ogbon pelu agbekale Yoruba to yanranti. O pe akiyesi awon eniyan si ibere ise fiimu ati ibi ti ise naa deduro. Bakannaa ni ko sai naka abuku si kudiekudie simina ode oni ati akoba ti n se fun awujo wa.
Boya ki n se gafara die na nibi, nigba ti n ma fayin le Ogbeni Oladeji Kehinde lowo.
Ogbeni Oladeji o ti ya o ...
Sinima-Àgbéléwo ti de ile yi ojo ti pe, èdòkì imo ti n fi n koni ni o je ki awon otokulu o ka kuro nile.
Hubert Ogunde se gudugudu meje ohun yaayaa mefa ninu sinima alágbàá, o ni ohun ti iShow Pepe ri ko to fori ró rukerudo iberepepe to doju ko atiwaye ere agbelewo.
Eyi o wu a wi, sinima Yoruba ti fese mule nile yii na, eni ti o dun mo ninu lo mo.
Ohun ta o mo la o mo, ohun to ba daniloju baa ba fogun e gbari ko leewo.
Lere Paimo ati Ishola Ogunsola ninu Ogbori Elemosho |
Ajani ati Asake ninu OLEKU |
Ohun Ogunde ni ko ma kin Iran Yoruba leyin ti fegun sowo, ere itage ti Duro Ladipo ni ko fe wa loju ti wa kata senu.
Iran wa ìí rinhoho; Asa Oyinbo ni. Awon sinima to n Jade laye ode oni ti n fowo ro asa wa danu a si jokoo a n woran. Yoruba o dun lenu awon onsere mo amulumala ede lo ku tiwon n so.
Ogunde ati awon osere re |
Lojoun ana, awon agba osere bi Ade Love a maa fi ere won kilo iwa ibaje, won a ma fi safihan awokose rere, apeere leree TOLUWANILE.
Se ti ka lo mo ara eni bi ejò lómógi ni ka so ni tabi ti ifenukenu, ifetekete , ìgbéñkanluñkan to gogo ninu Sinima-Àgbéléwo Yoruba ni ka menuba. Gbogbo re naa ni a n pe ni ere lasan.
Doris Simeon, Laide Bakare, Bimbo Akintola, Dayo amusa ati Tayo Odueke |
Ka fe wo sinima nile ka le omokekere jina ki oju majesin o ma ba a ribi, ka le tegbon-taburo siyara komo iya meji o ma baa rewele ninu fiimu. Omode o rekoo rere ko mo ninu Sinima-Àgbéléwo Yoruba, o se.
Muna Obiekwe ati Bola Ige lori itage |
Ere onihoho po bi bebesua, sinima gbébongbébon po ju iyanran. Omoge to ba sira sile ni i laamilaaka lode oni, eléhàá Nollywood o ni rise gba bòrò.
N o pe olaju o dara, n o si pe o leewo ka da aso igba fungba amo kama ríyàálé ka kòyàwó, ka ma folaju gbagbe orisun wa.
Yoruba ronu. Ki gbogbo oludari fiimu o sasaro, ka sun ka ronu bi awon ti tisaaju se bere ka ye toju ile mole.
----------------------------------------------------------------------
Too, oro leti gbo un lati owo Oladeji O. Kehinde. Ohun to koju si enikan, eyin lo ko si elomii. Kini ero ti yin?
0 comments:
Post a Comment