Smiley face

OLÙKÓ̩ FÁSITÌ O̩S̩UN TÍ WÓ̩N FI È̩SÙN ÀGBÈRÈ KÀN TI SÒ̩RÒ̩ Ó NÍ WÓ̩N FÉ̩ S̩ÀKÓBI ÒUN NI

- OLADEJI KEHINDE. 

Ò̩mò̩wé O̩labode Ojoniyi

OLÙKÓ̩ àgbà ti fásitì O̩sun ti sò̩rò̩ ó ní àwo̩n tí ò nífè̩é̩ òun ni wó̩n sàkóbá fún òun lórí fó̩nrán as̩emás̩e tí ó ní s̩e pè̩lú ìbálòpò̩ pè̩lú òkán lára aké̩kòó̩ inú ilé ìwé náà èyí tí ó ń tàn káàkiri orí káyélujára báyìí.

Ò̩mò̩wé O̩labode Ojoniyi ti è̩ka è̩kó̩ ìmò̩-è̩dá-èdè (Linguistics and Languages), fásitì Ò̩s̩un, ni óti wà ní inúfu-àyàfu báyìí nígbà tí ò̩kan lára àwo̩n aké̩kò̩ó̩ inú ilé-ìwé rè̩, Ikwe Ejiro Mercy, gbé fó̩nran kan jáde níbi ti olùkó̩ náà ti wà ní ìhòhò o̩mo̩lúàbí ní ìpalè̩mó̩ fún ìbálòpò̩ tí yóò wáyé láàrin òun àti o̩mo̩bìnrin náà. 

Ìròyìn tí a gbó̩ ni wípé Òjoniyi àti Mercy dìjo̩ ní àdéhùn àti pàde ní ilé ìtúra kan níbi tí wó̩n ó ti jo̩ fìgbádùn sayò̩ láyì mò̩ wípé o̩mo̩bìnrin náà ní èrò míràn ló̩kàn léyìí yóò kan lábùkù tí kò ní gbàgbé bòrò̩. 

Ohun tí ó ye̩ kó jé̩ ìbás̩epò̩ ìdákó̩ńkó̩ láàrín àwo̩n méjì yìí ní Mercy so di ohun tí gbogbo ènìyàn ń wò lórí è̩ro̩ ayélujára báyìí torí o̩mo̩bìnrin náà fi è̩ro̩ kò̩npútà rè̩ ká gbogbo ohun tí ó wáyé láàrín àwo̩n méjèjì nínú iyàrá náà sílè̩ tí ó sì fi sórí è̩ro̩ káyélujára. 

Bí ó tilè̩ jé̩ pé ìbálòpò̩ sàn-án ò wáyé láàrín wo̩n nínú fó̩nran náà àmó̩ a rí ò̩mòwé Ojoniyi tí ó jáde láti igun kan inú ìyàrá náà ní ìhòhò gedegbe tí ó sì ń bá Mercy dó̩wè̩é̩kè̩.

Onítò̩hún bèrè ló̩wó̩ rè̩ ó ní "kílódé ti nǹkan o̩mo̩kùnrin yín fi sorikó̩ báyìí, s̩é ó ti pé̩ tí e̩ ti s̩e é gbè̩yìn ni" òun náà sì da lóhùn pé ó ti pé̩ díè̩. 

Lé̩yìn ò̩re̩yìn Mercy gbé fó̩nrán náà sáfé̩fé̩ fún gbogbo ayé láti wò léyìí tí ó sì ti mú àríwísí jáde láti o̩wó̩ ò̩pò̩ ènìyàn lórí afé̩fé̩ tí àwo̩n alás̩é̩ ilé-è̩kó̩ náà sì ti gbé ìgbìmò̩ kalè̩ láti to̩pinto̩pin ìs̩èlè̩ náà.

Olùkó̩ Ojoniyi ti wá fè̩sùn kan àwo̩n ake̩gbé̩ rè̩ bí mélòó kan nínú is̩é̩ akadá pé àwo̩n ni wó̩n fi ò̩rò̩ náà s̩e àkóbá fún òun nípa lílo o̩mo̩bìnrin aké̩kò̩ó̩ o̩ló̩dún ke̩rin náà láti de̩ pàkúté fún òun. 

Ó ní o̩kùnrin kan tí ó ti fi ìgbà kan jé̩ olùkó̩ ní ilé-è̩kó̩ náà àmó̩ tí wó̩n dá dúró nítorí as̩emás̩e rè̩ ni ó lo o̩mo̩bìnrin náà láti fi ba òun lójújé̩. 

Lára àwo̩n tí ò̩mò̩wé náà tún fè̩sùn kan pé wó̩n ló̩wó̩ nínú ò̩rò̩ náà ni gíwá kó̩lè̩jì Adeyemi, ò̩jò̩gbó̩n Olukoya Ogen, òjògbó̩n Alebiosu O. C àti Akintayo D.I ti fásitì O̩s̩un. 

Ìwádìí ti bè̩rè̩ lórí ìs̩è̩lè̩ náà, ìgbìmò̩ tí ó ń bojú wo ò̩rò̩ òhún sì ti s̩èlérí pé àwo̩n yóò ri dájú wípé àwo̩n tú is̩u dé ìsàlè̩ ìkòkò.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment