#AyeOlabisiK22
Ẹ le ka itan igbesi aye Olabisi K to ti jade tẹlẹ NIBI ki ẹ to tesiwaju
lati ka eleyii ki itan naa le yeyin daada
Sii Olootu Yoruba Dun,
Mo koko fe fi asiko yii
dupe lowo eyin ti n e n fi asiko yin sile lati ka awon leta mi ti mo fi n ranse
si Olootu.
Bi mo se n ko awon leta mi yii ranse, bi itura lo n je fun okan mi
to ti kun fun ọgbé.
Ohun mo le fi we jo ki
eniyan ni eéwo, ki eéwo ohun wa n tu diẹdiẹ.
Mi o mo boya o ti seyin
ri, ki ohun kan ma gbe yin lokan tabi ohun ibanuje ọkàn, bi eniyan ko ba tun wa
ri eniyan ro fun, ẹdun okan nla ni maa je fun iru eni bee.
Opolopo ohun to sele si mi
ni mi o le ro fun awon ti won sun mo mi. Bi won tile soju aye niwaju mi, won le
da yeye mi sile ti mo ba peyinda tan. Fun idi eyi, mo dupe wi pe e je alabaro
mi.
Mo tun fi asiko yii dupe
lowo Olootu Yoruba Dun, ti won n daso ro mi- ti won bo mi lasiri- lati maa ran
mi lowo lati ma se atejade awon isele yii.
Ti won tun n gba mi ni imoran lori
ohun to ye ki n ma yo kuro ninu awon leta mi fun abo ara mi ati oruko mi. Mo
gba ladura wi pe ibanuje ko ni je ti won. Amin.
Ibi ti mo ba leta mi de ni
ibi ti oga mi ti fi tipatipa ba mi ni ajosepo. Gbogbo aso mi ti ya, o ti di
akisa mọ mi lara. Mo n wa ẹkun mu bi omi gaari loju kan naa.
Igba to ya, mo fi ọwọ
nu oju mi nu. Mo lo si inu baluwe yara kan naa ti mo wa lati lo fo ara mi nu.
Leyin ti mo se eyi tan, aso ko se wo sorun mo, gbogbo e ti di jalajala mo mi
lara.
Bi o tile je wi pe ile ti
su, sibe mi o le wo akisa yii jade bayii. Mo wo oju ago, ago mokanla ku die ko
lu. Mi o mo ohun ti mo le se, a bi ki n da aso ibora to wa lori beedi mora jade
ni? Mo gbe aso ohun wo lọwọ, n se lo wuwo bi awo erin.
Se mi o wa ni jade nibi
ni? Ko si wu mi ki n di ojo keji nile itura ajoji yii. Ati wi pe, bi mo di ojo
keji, ojo keji o wi pe ki aso to ti ya so mora won pada.
Mo ro wi pe ki ni mo le
se. Mo ranti ago ibanisoro mi ti o ti wa ni pipa lati igba ti awon okunrin meji
oloriburuku un ti gba lowo mi. Mo sure wa gburugburu lori beedi, mi o ri nibe.
Abi oga yii ti pada mu ago yii lo ni?
Ori beedi ni oga mi yii fi si leyin to
gba lowo awon okunri to gbe mi wa.
Ẹ tẹsiwaju ninu itan igbesi aye Olabisi K NIBI
0 comments:
Post a Comment