Oladeji Kehinde
Nibi ti awon kan ti n sunkun airomobi ni odaju abiyamo kan ti gbe awon
ibeji re junu si inu koto giriwo kan ni agbegbe Ajangbadi ni ipinle Eko.
Awon olopaa lati Ilemba Hausa division ti gbe oku awon Omo naa lo si ile igboku si. Gege bi ohun ti awon olopaa so, won ni nnkan bi aago kan osan ni awon ara adugbo naa pe awon lati wa wo isele to banininuje naa.
Eni
kan ti o soro pelu ibanuje okan lara awon agbofinro naa so wipe iyalenu
ni o je wi pe kaka ki awon eniyan ti o wa ni ibi isele naa doola emi
awon ibeji naa boya won le ye, nse ni gbogbo won mu ero ibanisoro won
Jade ti won si n ya aworan lorisirisi.
Awon agbofinro ti wa rin kaakiri gbogbo agbegbe naa boya won o ri eni ti o ni awon ibeji naa, tabi enikeni ti yoo fun won ni alaye ti yoo ran won lowo lori iwadii won, amo gbogbo-e-gbogbo-e pabo lo ja si.
0 comments:
Post a Comment