Bi ere bi awada, alaborun awon omo iko Boko Haram dewu mo Naijiria lowo. Igi taa foju rena ti n foni loju, gbogbo ogbon ta a gbon si ti n se bee di omugo. Ayafi oba Yaradu nikan lo le ko wa yo. Okan ninu awon oniroyin wa, Oladeji Kehinde, tun ti se akojopo iroyin nipa ibi ti n kan de duro lori awon iko Boko Haram. Abo iroyin naa re e lekunrere
Olórí ikò̩ alákatakítí è̩sìn ilè̩ Nigeria nì, Abubakar Shekau, ti sò̩rò̩ ó ní “bí ìjo̩ba àpapò̩ bá fé̩ kí á dá àwo̩n o̩mo̩bìnrin tí ń be̩ ní àkàtà wa kalè̩ àfi ki ìjo̩ba náà ó kó̩kó̩ dá àwo̩n o̩mo̩ ogun wa tí ń bé̩ ní ìhámó̩ rè̩ sílè̩ ní ayò̩ àti àláfíà”.
Èyí ni ìròyìn tí ó ń jà
ràyìnràyìn ló̩wó̩ báyìí tí ó sì ti ru ìrònú ò̩pò̩
àwo̩n onímò̩ sóké nígbà tí Shekau tún gbé fó̩nrán míràn
jáde gé̩gé̩ bí ìs̩e rè̩, níbi ti ó ti ń gba ìjo̩ba nímò̩ràn
pé bí wó̩n bá nífè̩é̩ àtí ̩fojú rí ̀awo̩n o̩mo̩bìnrin èyí
tí ó lé ní o̩gó̩rùn-un tí ń be̩ ni ìkáwó̩ òun àyafi kí
ìjo̩ba náà ó s̩e òun tí àwo̩n bèèrè náà.
È̩wè̩,
Shekau nínú ò̩rò̩ rè̩ náà fè̩sùn kan àwo̩n o̩mo̩ ológun ojú
òfurufu ilè̩ Nigeria pé wo̩n ń s̩eku pa ò̩pò̩ àwo̩n o̩mo̩ náà
nípa júju àdó olóró sí àwo̩n nínú igbò irunmo̩lè̩ tí wó̩n
farapamó̩ sí.
Àmó̩ s̩á o, àwo̩n ológun ilè̩ yìí tii sò̩rò̩
wó̩n ní ìhàlè̩ Boko Haram kò ní dá wó̩n dúró láti túbò̩
s̩e àko̩lù sí àwo̩n alákatakítí náà.
Àwo̩n
lóóko̩-lóóko̩ ilè̩ yìí nínú ètò ààbò àti ààjo̩ tí ó
ń léwájú tí ó sì ń polongo sétí ìjo̩ba fún ìdápadà àwo̩n
o̩mo̩ ilé è̩ko̩ Chibok náà, ìye̩n #BringBackOurGirls, ti wa késí
ìjo̩ba pé kí ó wá nǹkan s̩e sí ò̩rò̩ náà kí àwo̩n o̩mo̩
lè di rírí ní kíákíá.
0 comments:
Post a Comment