#AyeOlabisiK28
Ẹ le ka itan igbesi aye Olabisi K to ti jade tẹlẹ NIBI ki ẹ to tesiwaju lati ka eleyii ki itan naa le yeyin daada
Sii Olootu,
Mo ki yin wi pe e ku ojo
meta. Mo fe rawo ẹbẹ mi si gbogbo ololufẹẹ Yoruba Dun fun idaduro ọlọjọ pipe to
de ba leta mi. E fori ji mi. Ki i ku se wi pe mo ti ni awon leta mi yii nile
tele, mo kan an gbiyanju lati ma ko won diẹdiẹ ki n si maa fi ranse naa ni.
O wu mi ki n ti seri pada
lati igba yii wa, sugbon aye ni ko si fun mi. Bi o tile je wi pe ohun ti mo n
la koja lowolowo bayii ye awon Olootu, sugbon dandan ni fun mi lati toro
aforijin lowo eyin ololufẹẹ mi.
Ko ba wu mi ki n se alaye
awon idi pataki to fa idiwo fun mi, sugbon awon Yoruba ni gbogbo aso ko ni a n
sa loorun. A ti wi pe okookan la yose leku. Nitori idi eyi, e dakun, ori ikunle
ni mo wa.
Mo fe fi dayin loju wi pe
mo ti fi leta mi ranse si Olootu. Eleyii ti o je itesiwaju ibi ti mo ba leta mi
to kehin de. Sugbon Olootu gba mi ni imoran lati ko eleyii ti mo n ko yii saaju
ki won to se atejade leta mi tuntun naa.
Idi pataki si ni wi pe, won ni aimoye
eniyan ni o ti darapo mo Yoruba Dun eleyii ti won ko tile mo mi rara.
Bakan naa, awon ti won
tile mo mi, pipẹ ti leta mii pe le je ki won gbagbe ibi ti itan mi ti bẹrẹ. E
mi naa si ro wi pe ti mo ba kọ lati carry awon eniyan mi along, mo so erogba
kiko leta mi nu. Eleyii to je lati je ki awon eniyan ri ogbon kan tabi meji ko
ninu itan aye mi.
Fun idi eyi, mo ki gbogbo
eyin ti e n ka leta mi fun igba akoko. Oruko mi ni Olabisi K. Ile olorogun ni
ati bi mi, baba mi si ti se alaisi. Igba ti baba mi ku, awon ebi gbe ogun dide
nitori iya mi ni iyawo to kere ju. Omo meji pere si ni iya mi bi fun baba mi,
emi obinrin ati aburo mi okunrin.
Iya mi tiraka fun mi ki n le kawe gboye akoko ni ile eko giga. Olorun ba mi se,
kete ti mo pari ni mo rise. Idi ise yii ni ogun ti dide si mi. Oga kan ti won
gbe wa si ibi ise mi lo ni oun fe ba mi sun ni tipatipa. Mo ko jale, sugbon
leyinoreyin ohun meta lo sele si mi eleyii to je ibanuje ati ogbe okan fun mi.
* Oga yii pada ba mi sun.
*O da mi duro lenu ise.
*Bakan naa lo tun paro mo
mi wi pe mo ji eru ile ise pamo. O si setan ati je mi niya nipa riran mi lo sewon.
Eyin eniyan mi, di endi lo
pin sinima. Bi ko ba ti pari, njẹ eyin mo wi pe ko ti i le pari? Kilosele ni
ikeyin ohun gbogbo? Awon Yoruba ni, to ba ku die ki omo oloore jin si koto, won
ni monamona a se ise imole. Se monamona ohun pada tan a bi ko tan? Sebi won ni
bi oko ko jina, ila ki i ko. Eyin e saa ma ba mi bo, nitori won ni eni ba lo,
lo ba ku. A wa ko ni ku ni ase Eledumare.
Emi ni tiyin ni tooto.
Olabisi K.
Ẹ tẹsiwaju ninu itan igbesi aye Olabisi K NIBI
0 comments:
Post a Comment