#ayeOlabisi K 32
Ẹ le ka itan igbesi aye Olabisi K to ti jade tẹlẹ NIBI ki ẹ to tesiwaju
lati ka eleyii ki itan naa le yeyin daada
Mo lo gbọ esi ayewo ẹjẹ mi lọjọ keji lọwọ dokita.
Iberu ati iye meji ni mo fi wọ ofiisi dokita yii, ayo ati idunnu ni mo fi jade
nigba ti dokita so wi pe mi o larun kankan lara.
Mo ti ko asọ omobirin ile
tura yii dani. Bi mo se jade kuro ni ile iwosan, ọdọ rẹ ni mo gba lọ. Igba ti mo
fi oju mi kan an, mo dupe fun emi ifomoniyan se ati ife ti o fi han si mi. Bi
mo se n ki omobinrin yii lo n so wi pe ko tope. Mo nawo aso re fun, kaka ko gba
aso naa lowo mi n se lo fa mi ni tete lo si koro kan. O ni ki n joko ki ohun se
mi ni alejo.
Mo ko jale, sugbon omobinrin yii o gba fun mi. Mo joko, o si pada
lo ba mi mu elerin dodo kan wa fun mi, ki n mu. O joko ti mi, bee lo ro mi lati
so ohun to sele si mi gan-an ti mo fi deru ile itura. Mi o koko fe lahun,
sugbon nigba ti mo ranti iranlowo ti omobinrin yii se fun mi, mo ko gbogbo
alaye mo si ro fun-un lati oke dele.
Omobinrin yii se ileri
lati ran mi lowo. O ni oun ni egbon kan to je agbejọro. O ni ki n mọkan balẹ wi
pe ko ni na mi ni kọbọ. Ati wi pe oga yen ko ye ko lo lasan lai jeya ise buruku
to se. O ni pelu ẹri ti o ti wa lowo wa, o ni iyen lasan ti ran lewon alọramirami.
Bee lo se ileri wi pe oun bi eni kan yoo jeri tako oga yii ti a ba de kootu.
Ojo idajo ni kootu ti sunmo ju ti tele lo.
Omobinrin yii ni ki n ma lo, o ni bi
o ba ti je, oun yoo pe mi lori ago. O seleri wi pe bi oun ba ti kuro nibi ise
ni ọjọ naa, ile ẹgbọn oun ni oun yoo mori le.
Eyin ololufe Yoruba dun,
ibo gan-an loro to wa nilẹ pada yori si? Se ọga yii pada gbe faili yii sile ni
abi oro pada de ile ẹjọ? Nje agbejọro yii tile gba lati gba ẹjọ mi ro ni kootu?
Kilosele si ẹrọ akahunsilẹ ti ọrẹ ọkọ mi mulo? Ni agbara Eledumare, mo fi dayin
loju wi pe mi o tun ni i pe pada lati fun yin ni labare. E ku oju lona.
Emi ni tiyin ni tooto,
Olabisi K.
Ẹ tẹsiwaju ninu itan igbesi aye Olabisi K NIBI
0 comments:
Post a Comment