Ẹ le ka itan igbesi aye Olabisi K to ti jade tẹlẹ NIBI ki ẹ to tesiwaju
lati ka eleyii ki itan naa le yeyin daada
Sii Olootu Yoruba Dun,
Pẹlu iroyin ti ọkọ afẹsona mi gbọ yii, Olorun nikan lo mọ ohun ti
yoo jẹ èrè mi. Patapata ko yọwọkọwọ, lẹyinọrẹyin ko si maa ba tiẹ lọ. Sebi bi ọkọ
ba kọ ni ọkọ naa ni eniyan yoo pada fẹ. Sugbon ohun ti o se koko ju si mi ni
ayewo ti dokita so wi pe oun yoo se fun mi. Ki ori mi saa ko mi yo ninu ọfin aye
ti mo wa.
Igba ti ile mo ti dokita
gba ẹjẹ mi. Mo sebi ohun ti won yoo fun mi lesi kiakia ni. Dokita ni mo le pada
wa bi ọjọ keji lati wa gbo esi ayewo mi. O si fi damiloju wi pe kosi nnkankan
mo ati wi pe mo le ma lo si ile ni alaafia.
Bee lo gba mi ni imoran ki i n ye
maa pe lode mo nitori ẹni abi ire ki i rinde oru. Ati wi pe oru ko mọ eni ọ̀wọ̀.
Mo dupe lowo dokita, ore ọkọ mi naa lo san gbogbo owó ti won kọ fun wa pe ka
san.
Nigba ti a jade sita ni ile
iwosan, mo beere lọwọ ore ọkọ mi pe ki ni sise leyin igba ti eri ti a n wa ti tẹwa
lọwọ.
O ni ki n fun ohun laaye
naa ki ohun sise lori ero ikahunsile naa ka to mo ohun ti yoo sele. (O fe se
eda ohun ti a ka sile naa sori foran C.D)
Mo gba ile lo. Igba mo
dele, mi o ba iya mi ati aburo mi. Won ni won ti ji lo sibi akanse adura kan.
Enu mi ko tile ran ounje kankan. Mo kan saa tun pada sori ibusun mi ni.
Ki se
wi pe orun lo n ku n kun mi, mo kan ronu naa ni. Bi igba ti mo n wo fiimu ni
gbogbo re jo loju mi. Lori ero yii ni mo wa ni ipe oko afeson mi wole. Gbogbo ohun ti o tile n so lori foonu o tile
ni itunmo gidi si mi rara. Ohun ti mo le ranti ko ju wi pe mo ranti wi pe o
beere wi pe se alafia ni mo wa. Mo si so fun wi pe mo wa ni alafia.
Ko bere bi gbogbo re se
lo, emi naa o si se alaye kankan. Leyin eyi ni mo pe omobinrin ti o fi aso bomi
ni asiri ni ile itura. (Mo gba number re
ki n to kuro nile itura lojo naa). Mo pe wi pe mi o ni pe ma ko aso re bo.
O ni ki n ma se iyonu, oni ohun ko si ni eni
ise bayii, wi pe mo le ko wa lojo keji.
Mo du pe lowo re. Ile ti mo wa ni yii
ti iya mi ti de ba mi. Mo ko ejo mo ro fun iya mi. Titi ti ile fi su ni
ojo naa, omi ekun ni emi ati iya mi n wa mu bi eni wa gari mu.
Mo gba adura fun gbogbo
eyin oluka leta mi wi pe e ko ni rogun ekun, ibanuje ko ni ya ile yin ati ode
yin. Amin.
Ẹ tẹsiwaju ninu itan igbesi aye Olabisi K NIBI
0 comments:
Post a Comment