#ayeOlabisiK30
Ẹ le ka itan igbesi aye Olabisi K to ti jade tẹlẹ NIBI ki ẹ to tesiwaju lati ka eleyii ki itan naa le yeyin daada
Yoruba Dun: Itan igbe aye Olabisi K (30) |
Sii Olootu Yoruba Dun,
Mo tun fi asiko yii ki
gbogbo eyin ololufe mi lori Yoruba Dun. Adanwo kekere ati eyi to tobi ko ni deba
yin. Ti a ba wa ri eni to n la n isoro kan tabi ekeji koja, Olorun Oba alaanu
yoo gbe won gori gboogbo isoro won patapata. Oba to ba okun soro ti okun gbo.
Oba to ji oku ojo meta dide ninu isa oku. Olorun oba to n gbo adura yoo gbo
adura gbogbo wa.
Awon Yoruba ni ti ina ko
ba tan laso, eje ki i tan ni eekanna. Ibi a si roko si ti, ibe naa ni a n fabo
si. Leyin igba ti oga mi fi tipatipa ba mi sun tan ni ile itura yii.
Ore oko mi
pada wa ba mi, awa mejeeji si kori si ile iwosan ni ale ojo naa. A paro fun won
ni ile iwosan wi pe awon omo asunta kan niwon dena demi, ti won si fi tipatipa
ba mi sun. Dokita fi wa lokan bale wi pe kosi iyonu, ati wi pe oun se itoju mi
bo se to ati bo ti ye.
O fun mi ni ogun ti i dena
oyun airotele. Bakan naa ni won fun mi beedi wi pe ki n sun si, nitori pe mi o
le lo si ile mo. Dokita tun fi ye mi wi pe oun yoo se ayewo kokoro aisan
koogbogun ti a mo si HIV fun mi.
Eleyii jami laya pupo
nitori wi pe onisekuse eniyan ni oga mi, awon irin re ko si mo. Niwon igba ti o
je wi pe eniyan o le ti bi oju mo eni ti o ba ni arun kogboogun, bi oga mi tile
ni lara bawo gan-an ni mo se fe mo. A fi ki Olorun alaanu se anu re fun mi. Abi
iru adanwo wo leyii?
Ki n si ti mo ki n ti bo
sile ninu ọkọ nigba ti awon oloriburuku okunrin ti won wa gbe mi so wi pe mo ni
anfaani lati bọ sile ninu ọkọ awon ti ọkan mi o ba lọ mo.
Mo wa lori beedi nibi ti
mo sun si ti mo n ka oke aja. Orisiirisii ero lo n wa si mi lokan. E gbona, ti
o ba lo je wi pe mo ti ko arun yii lotito, se temi o ti ba je patapata bayii?
Iya ko toya, afada pakun, ada sonu, ikun tun dohun airimo.
Mo saa fi okan mi
gba adura. Igba yii ni mo se akiyesi wi
pe ore oko mi o si pelu mi mo. Igba to ya die lo wole wa. Mi o mo ohun to n se
nita to fi pe too bee. Mo beere boya ọkọ afesona mi ti pe e pada.
O si je ko ye mi wi pe o
ti pe oun pada. Ko so ju bee lo fun mi. O le je oko afesona mii naa lo n ba soro
to fi pe to bee nita. Tabi sugbon kan ko si nibe, gbogbo ohun to sele pata ni
won ti bara won so lori foonu. Oro naa ba emi gan-an alara lokan je.
Imi kekere
leti awo gbegiri, ka nu kuro ka maa jeun lo. Bi o ba kuro loju. Ko le kuro
lokan. Amo kini kan lo dami loju, bi a ba sare ki oju ma ti ni, ti oju ba ti
ni, are ka maa ku ni kan loku.
0 comments:
Post a Comment