#ayeOlabisiK34
Sii Olootu,
Bi ẹ ko ba gbagbe ibi ti mo ba leta mi de. Mo
ti se alaye bi ore mi tuntun ti o je osise ile itura se setan lati ran mi lowo
nipa iranlowo lati odo egbon re ti o je agbẹjọrọ.
Bi o tile je wi pe mi o ti
gbo abo re, boya egbon re gba lati ran mi lowo abi beeko. Eyi yowu ko je, mo
saa fi okan mi si odo Olorun ti n ba eda gbe eru to wuwo.
Ati wi pe sebi adehun ti o
wa laaarin emi ati oga mi ni wi pe bi oun ba le ba mi sun, oun yoo je ki won fagi
le ẹjọ mi. Sebi won ni asoti oro ni i je omo mi gbẹna.
Ati wi pe, won ni eni mo ati waye Oluunago ni
o mo ati lo re. Oga mi lo gbe faili yii pamo, oun naa ni o si wa jade.
Ohun kan to tun ba mi
lokan je ni wi pe, oko afesona mi ko pe mi mo bi i ti tele, ayafi ti mo ba flaṣi
ẹ ni yoo to pe mi pada. Ati wi pe, igba to da fun mi wi pe oun yoo pada ti
koja. Se kase intafiu ka pada ni adehun emi ati e.
Ominu n komi, sungbon awon agba
loni ti igi ba re lugi, ti ori re la a ko re kuro. Ti mo ba ro oro oko afesona
mi fun igba die, maa tun gbe kuro lokan. Ko maa je wi pe oro awon agba ti fe
maa se mo mi lara.
Won ni owo epo laraye bani la, kosi eni ti n ba ni lawo ẹjẹ.
Bee won lore kosi mo, abanirin loku. Sugbon eni afeyinti bi o ba ye wiwi ni wi.
Boya ka tile diju bi eni to ku, ka wa wo eni ti o se idaro leyin eni. Ka
burinburin ka fese ko gbau, ka wa wo eni ti o se ni pele. Ajumobi ko kan taanu,
eni ori ran sini lo n seni loore. Bi mi o tile ri oko afesona mi, ore re n
gbiyanju fun mi pupo.
Mo gbiyanju lati ri ore
oko mi nipa ohùn oga mi ti a ka si ori ero ti o so wi pe oun fe se eda re si
ori fonran. O wi fun mi wi pe gbogbo oun taafe lo jade ketekete.
Bi o tile je wi pe oro ti
yi pade. Ero wa tele ni wi pe boya a le dabi ọgbọn ti oga mi ko ni ri mi ba
sun, ti asiri re yoo si tu si wa lowo.
Sugbon niwon igba ti o ti je wi pe aaya
gbọn Ogungbe gbon, aaya n tiro, Ogungbe naa n bere. Ogbon ti oga mi n dasile de
wa ju eyi ti awa ro lokan lo.
Bi o oro si ti wa ri bayii, e je ka gba wi pe mo
fi ara mi sile fun un gege bi ife oga mi. Adehun wa si ni wi pe, ti mo ba le fi
ara mi sile fun oun, ẹjọ ti pari.
Sugbon ohun re ti a ka sile
si wulo, nitori ojo ti n ro ti o ti da loro to wa nile yii, ko seni to moye eni
ti yoo pa.
A si ki i gbo kuku ojo ka wa daminu àgbá nu. Ti oga mi ba gba lati da faili yii pada, ti
won si fagi le ejo. Oro ti buse. Gbogbo iyoku, iso inu eku ni.
0 comments:
Post a Comment