#ayeOlabisiK35
Mo ti n ri eniyan laye,
ore oko afesona mi tun jomi loju. Gbogbo igba ni o maa n fun mi lówó ki n maa
ri ohun na. Igba mii yoo fi kaadi ipe
ranse si ori foonu mi.
Bi o ba wa ki mi nile, ọpọ igba ni yoo ba mi ra
orisiirisii nnkan dani bi jije ati awon nnkan lilo. Bee lo tun maa n so fun mi
wi pe ti mo ba niilo ohun kan ki n ma je ki ohun gbo.
Bi o tile je wi pe oun o
ni pupo, sugbon ninu die ti oun ni, oun yoo maa se fun mi gege bi o ti ye. Won
tile ji foonu mi nibi mo ti n saaji re, nibi won ti n wo boolu legbe ile wa.
Kosi ina lale ojo naa, won si tan jenerato nibe, ni mo ba fun enikan ti mo mo
pe ko ran mi lowo.
Alọ foonu mi ni mo ri, mi o rabọ re. Opelope ore oko afesona
mi ti o ra Nokia C3 mii fun mi. Ti mo ba ni o ti poju, ani iyawo awon ni mo je,
oun si gbodo maa se itoju mi daradara, agaga nigba ti ore oun ko si ni itosi.
Mo gbiyanju lati pe oga mi
yii lori ago ni irole ojo keji leyin ti ore oko mi ti fi mi lokan bale wi pe
awon ohun oga mi yii ti a ka ti dori foran.
Mo tile sebi boya koni gbe foonu mi ni, owo kan ti foonu naa dun logbe
e.
Oga mi: Hellooooo
(Ohun tutu toki ni were
ara re fi n seloo lori foonu. Bee ni mo n fokan fun lepe, olori buruku
masanfaani. O ko ni ku pe)
Emi: Hello sir, mo ni ki n
pe yin lori adehun wa ni.
Oga mi: (Were ara re dake
lo gbarii ko to fesi. Bee ni n fa ohun re gun bi eni to sese n jibo loju
orun) A.d. e.h.u.n.
w.o ni y.e.n oo? E jo, taani mo n ba soro na?
Emi: (Mi o tile mo iru epe
ti mi o ba se fun-un were ara re nitori wi pe o ti n munu run mi bo ti n fun mi
lesi awon oro re. Sugbon mo dehun fun, mi o fu lara wi pe inu ti n bii mi) Emi
Olabisi ni, sebi e so wi pe e maa da faili pada leyin igba ti mo ti fun yin ni
ohun ti ẹ n fẹ.
Oga mi: heheheheh..
Olabisi? (oun sebi eni to sese ranti mi) Iwo ni. Ha, mi o mo pe iwo ni. Bawo ni
nnkan? Mi o de ri e mo?
Emi: oga, ohun ti mo bi
yin ni ke e dami lohun o. Se e ko ni gbe faili yii sile mo ni abi bawo?
Oga mi: Wo…wo! Ma pariwo mo
mi. Faili ewo ni won n gbe sile? O je lo
gbe faili wa nibi to ba mo wi pe o gbe si. Ti o ba de ri gbe sile, awon to ni
faili to gbe pamo maa pade e ni ile ejo. Ewo ni temi ti o n pe?
Oloriburuku e o duro gbesi
ti o fi pa ago mo mi leti. Mo pada pe ago re ko gbe mo. Mo pe ago yii titi ko
gbe ago naa. Igba to ya lo pemi pada pelu nomba ajeeji.
Oga mi: (Ibinu lo fi n
soro fatafata) Wo, gbogbo bo se n ba mi loruko je kaakiri ni mo n gbo, bi o ba
de stop e, ohun ti maa se fun e, titi lai o ni gbagbe rara.
Emi: Oruko yin won ni won
ba ja? Ohun ti e n wa leyin akosu, e ba leyin ewura. Ke e lo gbe faili te gbe
sile ti e ba fe wahala. Abi ki le tun fe gan-an (mi o mogba ti mo bu sekun
peregede).
Oga mi: woo, ma sun kun
eke si mii leti. O sese bere eekun ni, ohun ti ma foju e ri, ni ile aye o ni
gbagbe. Last warning ni mo fun e yii, mii o gbodo tun gbo oruko mi nibikibi.
Ayafi ti o ba fe pare lojiji.
Emi: Emi o ni pare loruko
Jesu, iwo lo maa pare. Olori buruku…(o pa foonu mo mi leti).
O si n tẹsiwaju...
0 comments:
Post a Comment