Ẹ le ka itan igbesi aye Olabisi K to ti jade tẹlẹ NIBI ki ẹ to tesiwaju lati ka eleyii ki itan naa le yeyin daada
Eyin ololufee mi ninu Yoruba Dun, mo fe so fun yin wi pe ojo ti inu mi baje ju laye lojo ti mo padanu baba to bi mi lomo.
Sugbon ibanuje ti mo ba pade lowo oga mi lale ojo ti mo n so yii tun ju irora iku baba mi lo. Oga mi ya aso mo mi lara, gbogbo aso ara mi di akisa. O si fi tipatipa ba mi lajosepo. Mo tile n janpata tele, ti mo n ko ese ati igbaju bo lori.
Igba to ya lo re mi, mi o si ni okun lati le janpata mo. Eyi si fun ni anfaani lati semi boti fẹ.
Igba ti oju rẹ wale. O dide lori mi. Bẹẹ lo bu sẹrin iyangi. O fi ahon dan ete rẹ la lébé bi igba eniyan sese la oyin tan. O ni sebi emi so fun oun wi pe virgin ni emi ni gbogbo igba ti oun ba mi soro.
Inu mi baje, mo si sunkun ibanuje ti mi o sun ri laye mi.
Bi o se n fimi se yeye loju kan ti mo wa yii bee naa lo n sare wo aso re. O wo yika yara naa boya ohun kan wa to ye koun mu, o si ri wi pe gbogbo ohun to ye ki oun mu ni oun ti mu. O sa jade ninu yara yii, Inu mi ba je, mo si bu sekun.
Inu mi ba je de ibi wi pe, mo n ro bi eni wi pe ki n pa ara mi sinu yara yii. Mo si pinnu wi pe ninu yara nibe ni ma ti gbe pokun so.
Awon Yoruba ni imi kekere leti awo gbegiri, ti a ba nu kuro, bi o ba kuro loju, ko le kuro lokan. Oro ile aye mi su mi, mo sunkun gbogbo agbari lo san mi bi igba won lagi lori mi.
Eyin temi, e je ki n tun danu duro nibi. Mo n bo laipe lati so oun ti mo fi ohùn oga mi ti mo gba silẹ se.
Se oga mi gbe faili yii sile tabi ile ejo naa ni a pada ti pade? Gbogbo bi o ti sele pata ni ma se alaye fun yin.
E ku oju lona.
Ẹ tẹsiwaju ninu itan igbesi aye Olabisi K NIBI
0 comments:
Post a Comment