Smiley face

Yoruba Dun: Itan igbesi aye Olabisi K (19)


Yoruba Dun: Olabisi K 19


Leyin eyi, oga mi seju si awon okunrin meji yii wi pe kii won o maa lo.

"Oya, jẹ ka sare se ohun ti a fẹ se. Ti a ba pẹ ju lori imi, eesin keesin ni kani mọbẹ" oga mi lo soro bayii.

"Ka sare se ohun ti a fẹ se, a bi ki ni mo gbọ ti ẹ wi? Se ohun ti ẹ se daa, oga?


Tori wi pe a fe ba mi ni ajosepo ti mi o gba, ẹ da mi duro lẹnu ise, ẹ tun parọ mo mi. Iya le fi n jẹ mi yii o, Olorun yoo si se idajo laaarin emi ati yin."

"Woo, mi o wa rojo, ti o ba je wi pe ejo lo wa ro mi o raye rara. O saa ti gba lo fi wa bi? Kilo wa tun fa aroye ẹjọ ti ko ni itunmo? Damilohun kia mi o lakoko pupo o."

"O ri wi pe e fe ba mi sun yii naa ni ẹ si wa. E yii lo mu yin gbe faili pamọ ti ẹ wa ni emi ni mo ji faili ile ise wa gbe? Bi afehin pẹran ti yin ba pin tiẹ, Olorun oba a maa tun pin o. Mo si fe ki e beru Olorun- Olorun oba adekedajo."

"Iwo arabinrin yii, da mi lohun, mi o ra ye ẹjọ wẹwẹ."

Saaju ki a to ma so awon oro wonyii. Ni kete ti awon okunrin meji yen ti jade, ni oga mi ti ti ilekun lati eyin. O fi kokoro si egbe beedi, ni egbe re, ohun naa si ti bo si ori beedi funfun nla to wa ninu yara naa.
"Ọga, Se eyin naa mo wi pe irọ le pa mo mi? Se ẹmo lokan ara yin abi e ko mọ bẹẹ? E paro mo mi tori wi pe mo ko lati gba ki e ba mi sun?"
Mo sakiyesi wi pe ara n fu pelu awon nnkan ti mo n beere yii, ara fu bi eni wi pe mo fe ko soro si mi lowo ki n le ri nnkan ka sile.
Sugbon ko ri nnkan to je mo ẹrọ igba-ohun-sile lọwọ mi eyi si n se ni kayeefi, bi o tile je wi pe ko fi enu re so jade fun mi.

Gbogbo bi mo ti n wi yii lo saa n tenu mo ki n da oun lohun, ojo nlo. Sugbon lokan mi, mo ro wi pe iwomba eri ti mo ti rigba naa ti to fun mi gege bi eri lati tako okunrin yii. Nitori wi pe gbogbo ohun ti won ni mo se ko tako mi wi pe ko ri bee.

Leyin eyi, mo n ro ona ti mo le gba sa mo o lowo. Mo beere sinu sunkun arumoje kan.

Igba ti mo se akiyesi wi pe o ti gbagbe arare, lojiji ni mo sare sumo ki n le mu key to wa legbe re, ki n silekun ki n ma salo. Bi mo se fe se eyi lo ra mi mu.

Mo fi ariwo bonu, ki ohun mi to goke debi ti mo fe, o ti fi tipatipa fi owo bo mi lenu. Agbara tie bori agbara ti mo ni. (Mo gbagbe ki n so eleyii, ori oke patapata ni yara ti oga mi gba si ile itura yii wa)


Ẹ tẹsiwaju ninu itan igbesi aye Olabisi K NIBI
















Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment