Ẹ le ka itan igbesi aye Olabisi K to ti jade tẹlẹ NIBI ki ẹ to tesiwaju lati ka eleyii ki itan naa le yeyin daada
Igba to se die, motor yii ya wole si oju ona agboole kan. Titi eleruku ni titi agbole naa. Igba ti ala titi agboole yii ja doke de ibi ti opin si, a tun ya si apa otun, a wa lo gẹrẹgẹrẹ ni owo isale. Igba ti a de enu ile kan ni motor naa aduro.
Bi hotel naa ni a le pe iru ile yii. Sugbon gbogbo rẹ gbẹ furufuru, ko tile jọ hotel loju temi, bi ile atijo ni ile naa jọ. Awon ọda ile naa ti n sibọ diẹdiẹ lara iganna.
Boya gan an ni won tile ni onibara rara. Sibika nla ti n korin pelu awon aga ofifo funfun ti won to kale lairi ẹni ba won jokoo le lori lo n ki wa kaabo lẹnu abawole.
Awon okunrin meji yii mu mi wole lo si ibi ti oga mi yii wa. Igba ti a foju kan oga mi yii nibi to wa, o rerin muse si mi. Sugbon mo ko oju mi nile fun un. Mo si leju pa bi eni ti won so pa.
Awon okunrin yii fi foonu ti won gba lowo mi ninu motor le oga mi lowo. Oga mi sun mo mi, o si ja baagi mi gba lojiji, o da gbogbo ohun to wa nibe sile.
Gbogbo ohun ti mo ko sibe si fon ka gbogbo ile kaakiri.
Eroja isaraloge: gilasi ilewo, itọju ati itọte, atike funfun, pafiimu ati iyarun. Lara ohun to dasile ni ṣaja foonu mi, ati five hundred naira meji.
Mo duro legbe kan mo n wo gbogbo ara ti oga mi yii n da. Mo se akiyesi wi pe ara n fu oun gan-an ju bi mo se lero lo.
Bee lo si han gbangban wi pe oun naa n bẹru nitori wi pe ko mo ibi ti mo fe ba yo si oun, ko si mo iru imura ija ti mo mu wa ba oun. Nigba ti o je wi pe ki i se ife okan mi ni mo fi wa ba ni ile itura.
Aaya gbon, Ogungbe gbe gbon ni oro emi ati tiẹ. Aaya n tiro, Ogungbe n bẹrẹ. Bee ibi won foju si ona ko gbabe lọ. Ohun ti o lero ni wi pe ni boya oun yoo ri ohun ifura kan ninu apamo mi to jagba.
Boya bi nnkan olóró, ohun ija, tabi ohun ti o le se akoba fun un.
Okan temi naa ko balẹ rara, nigba ti mo ti mo iru ise ti emi naa fe se. Amo ibi won foju si ona ko gbabe gege bi mo ti sọ saaju.
Rikọda ti mo mu dani, ori ọrun ọwọ́ mi lo wa. Ohun gan-an ni mo de mowo bi ago. Bi won ko ba so fun eniyan wi pe ki i se ago, ko si eni to le mo laelae.
Emi ti won mu fun gan-an o gba, a fi gba ti won danwo loju mi ki n to gba wi pe looto wi pe ero igbohun sile ni. Lowo okunrin oniroyin kan ni ọrẹ oko mi ti ba mi ya.
Leyin eyi, oga mi seju si awon okunrin meji yii wi pe ki i won o maa lo.
Ẹ tẹsiwaju ninu itan igbesi aye Olabisi K NIBI
0 comments:
Post a Comment