Ẹ le ka itan igbesi aye Olabisi K to ti jade tẹlẹ NIBI ki ẹ to tesiwaju lati ka eleyii ki itan naa le yeyin daada
Mo pa okan mi po, bẹẹ ni motor ohun tun bọ n sare lo lẹlẹ ninu okunkun birimubirimu.
Gbogbo ona ti a n to lo se ajoji simi, boya to ri ale to je ni, tabi iberu to ti joba lori okan mi ni, tabi tori ai ki i jade mi lofa a ti mi ò fi mọ awon adugbo naa dojudoju.
Mo tile n fi ogbon wo ita boya maa ri signboard kan ti won ko address si ti o jẹ ki n mo ibi ta a wa gan-an.
Sibe naa nko, oye ni mo fi n gbe, oju mi ko da si awon ona yii daradara.
Igba to ya la kan awon olopaa ti won ma n gbegi dana. Kete ti mo ri won ni okan mi tun gbefuke soke. Orisiirisii ero si n sare wa simi lokan.
Awon olopaa tan ina touch light sinu motor nigba ti a kan won lara. Mi o mo boya ki n pariwo ki awon olopaa ran mi lowo. Boya ki n pariwo wi pe won fe jimi gbe lati lo pa mi. Amo eru n ba mi, mi o mo bi mo se fee kigbe soke sọrọ.
Ti mo ba kigbe soke, ti won awon olopaa ba mu awon okunrin mejeeji yii, bi won tile jẹwo bi oro seri fun awon olopaa. Sugbon ti ẹni to ran won nise ba sẹ wi pe oun ko mo won ri nko?
Bowo ni ki n ti se? Tabi to ba pada yi i le mi lori wi pe, ète ati ba oun loruko je ni mo n da.
Mekunnu ti n ba olowo lagidi, ajekun iya ni o je. Mi o mo ohun ti mo le se nibi ti mo wa yii.
Nibi ti mo ti n ro awon ero yii lowo ninu okan mi, ni eyi ti o wa niwaju (driver ti o n wa motor) ti sowokuduru fun awon olopaa. Mi o moye ti o fun awon olopaa yii.
Sugbon owo to joju ni lo ni lati je. Nitori wi pe ni ọwọ kan ni olopaa yii ni ko carry go pelu erin ati oyaya. Dẹrẹba fi motor si gia, bee lo tun tena pa gege bi o ti n se tẹlẹ.
Sugbon, e duro na, ti mo ba ni ohun ti oga mi fe se ni yii, ti o ba lo yato nko? Ti mo ba ni tori wi pe o fe ba mi sun lo se ni ki n wa, to ba je wi pe o fẹ pa mi ni nko?
Bakan meji ni ọrọ yen ni lati je. Nitori wi pe oga topa aduru iro nla bayii mo mi, kini idaniloju wi pe ko le pami ti o bari idi pataki lati se bee?
Mi o le so wi pe iye ago bayii lolu, amo ohun to da mi loju ni wi pe ile ti su daada.
Igba to se die, motor yii ya wole si oju ona agboole kan. Titi eleruku ni titi agbole naa.
Igba ti ala titi agboole yii ja doke de ibi ti opin si, a tun ya si apa otun, a wa lo gẹrẹgẹrẹ ni owo isale. Igba ti a de enu ile kan ni motor naa aduro.
Ẹ tẹsiwaju ninu itan igbesi aye Olabisi K NIBI
0 comments:
Post a Comment