Ẹ le ka itan igbesi aye Olabisi K to ti jade tẹlẹ NIBI ki ẹ to tesiwaju lati ka eleyii ki itan naa le yeyin daada
Sii Olootu Yoruba Dun,
Mo fi asiko yii ki gbogbo ẹyin ololufẹ Yoruba Dun ku odun tuntun. Ni agbara Olorun, ọdun ayọ ati igbega nla ni odun tuntun yii yoo jẹ fun gbogbo wa. Wahala to kere, wahala to tobi ko ni ya ile ẹnikẹni ni agbara Olorun.
Sebi won ni bina ko ba tan lasọ, ẹjẹ ki i tan leekanna. Mo ti pinnu lati salaye ohun oju mi ri lọwọ ọga mi fun gbogbo ẹyin ololufẹ Yoruba Dun.
Bi mo ba si kọ lati fẹnu ọrọ mi jona, a je wi pe mo ti dalẹ ife ti ẹ ni simi ni yẹn.
Amọ ohun kan lo da mi loju, eniyan ko ni taja erupẹ laye ko ma gbowo okuta. Tori o je ọga le mi lori, ti o si lagbara ju mi lọ, o fẹ lo ipo rẹ lati fi yan mi jẹ nipa biba mi sun ni tipatipa. Mo kọ jalẹ, eleyii lo si fa wahala si mi lagbada.
Mo ko jale lati gba ẹgbin to fi lọ mi yii, lo jẹ ko da mi duro lẹnu isẹ. Bakan naa lo tun parọ mọ mi lati ran mi lẹwon ti mi o fẹ lọ.
A mo ibi eniyan ko si, Olorun oba oke wa nibẹ. Oba adekedajọ yoo si se idajo onikaluku bo ti tọ ati bo ti yẹ.
Bi o si je wi pe emi naa ni mo n we irọ mọ ọga mi lẹsẹ, sebi Olorun oba wa loke to n wo gbogbo wa. Ni o si se idajọ bo ti tọ ati bo ti ye.
Bi awon ọmọ okunrin meji yii se n gbe mi lọ ninu alẹ dudu yii ni okan mi n lu kikiiki, bẹẹ ibẹru ko je ki n le mi doke ati silẹ daada.
Gulegule ni mo n mi bẹẹ ni mi o si fe ki ara fu won wi pe aya mi n ja.
Mo ti ri aridaju wi pe ète ti won da silẹ de mi ti ga ju ète ti emi ni lọkan lọ. Ki ni idaniloju wi pe gbogbo asiri mi gan-an kọ ni yoo pada tu si won lọwọ nipa mimọ wi pe mo mu ẹro ti n gba ohun silẹ dani lati rikọọdu ohun won silẹ.
Ibi to ba le wu ko jasi, eniyan ki i kanlu odò ko tun ma kerora otutu. Ko si igba ti Maku ko ni i ku. Ina ti jo de ori koko bayii. Iduro ko si, ibẹrẹ ko si fun ẹni o gbodo mi.
Ẹ tẹsiwaju ninu itan igbesi aye Olabisi K NIBI
0 comments:
Post a Comment