#AyeOlabisiK23
Ẹ le ka itan igbesi aye Olabisi K to ti jade tẹlẹ NIBI ki ẹ to tesiwaju
lati ka eleyii ki itan naa le yeyin daada
Yoruba Dun: Itan igbesi aye Olabisi K (23) |
Mo ro wi pe ki ni mo le
se. Mo ranti ago ibanisoro mi ti o ti wa ni pipa lati igba ti awon okunrin meji
oloriburuku un ti gba lowo mi. Mo sure wa gburugburu lori beedi, mi o ri nibe.
Abi oga yii ti pada mu ago yii lo ni?
A se o ti jabọ sẹgbẹ beedi
lodi keji lohun ni. Mo pada ri nibi to jabo si, nibi ẹsẹ beedi. Bi mo se tan lo
muna wa, ago naa seju lebelebe. O sese n gbera so ni. Igba to ya ni ina re mole
kedere, eleyii to fihan wi pe o ti tan tan. Ki n to gbiyanju ati te ohunkohun,
atẹjise bi mefa lo sare wole leekan naa.
Mo ri ti oko mi, ati ti
ore oko mi. Mo ro wi pe igba ti ore oko ko mo ibi ti won gbe mi lo, lo mu pe
oko mi. Awon oloribuku si ti gba foonu lowo mi ni gbogbo igba yii. Boya igba ti
oko afesona mi naa gbiyanju titi ti ko ri mi ba soro lo je ko fi atẹjise sori
ago mi.
Mo mọ lokan mi wi pe ore
oko afesona mi o ti daamu ju bo ti ye lo. A ti wi pe inu aibalẹ okan ni yoo wa.
Nomba tie ni mo sare pe.
‘Hello, ibo lowo ataaro ni
mo ti n try number ẹ. Se Alafia lo wa sa?’
Pelu itara ati iberu ni
ore oko mi fi n soro lodi keji loun. Mi o tile mo ohun ti mo le so fun gege bi
esi oro re. N se ni mo bu sekun peregede.
“ Kilose e, ba mi soro
now. Ibo lo wa bayii? Ba mi soro se?”
Bi ti n soro lo n re mi
lekun, bee ni omi n jade loju mi poroporo. Mi o tile mo bi mo se fe fi enu soro
wi pe oga oloribuku yen ti pada fi tipatipa ba mi sun.
“ Alafia ni mo wa”. Mo
pada soro leyin ekun mi.
Mo wi fun wi pe alafia ni
mo wa sugbon ko ma bo wa ba mi nibi ti mo wa. O beere ibi ti mo wa gan-an,
sugbon emi gan-an o le so pato ibi ti mo wa.
O ni se mo le ri eniyan kan bi, ti
mo ba ti mo ibi ti mo wa, mo le pe oun pada ki oun le tete ma a bo wa ba mi. Mo
se ileri fun wi pe maa gbiyanju, mo si pa ago mi.
Mo gbe ago kale, mo ri
telifoonu iletura lori tabili, eleyi ti won fi ma n pe awon osise ti eniyan ba
fe ounje tabi ohun kan. Nomba ti eniyan o pe wa lori tabili legbe foonu
alasomolẹ naa.
“Hello, e jowo ki ni mi le
se fun yin.” Ohun obirin ni ohun ti mo gbo. O si mu inu mi dun, tori obinrin lo
le se iru iranwo ti mo fe.
“E jowo anti, mo niidi
iranlowo yin”
“Ok, ko si wahala. Ki ni
mi le se fun yin gan-an”
“E jowo, mo fe ki e yoju
si mi ni, e jowo, e ma binu”
“Ko si wahala, enikan ma wa
ba yin”
“Enikan ke? Eyin gan-an
gan-an ni mo fe. E jowo, e ma binu. E jowo, e yoju si mi.”
“Ko si wahala, kini nomba
yara yin”
“Nomba yara mi?” Mo gboju
wo eyin, lara kokoro enu ona. Keyholder nla ti won so kokoro mo, ara re ni nomba
yara ti mo wa wa: “ Nomba 021”
“Ok, mi bo wa ba yin”
Ẹ tẹsiwaju ninu itan igbesi aye Olabisi K NIBI
0 comments:
Post a Comment