#AyeOlabisiK24
Ẹ le ka itan igbesi aye Olabisi K to ti jade tẹlẹ NIBI ki ẹ to tesiwaju
lati ka eleyii ki itan naa le yeyin daada
Ìgbà to to isẹju bi meji, ẹnikan
kan ilẹkun yara ti mo wa ko..ko..ko.
“Ẹ wọ le”.
Ọmọbirin pupa kan lo wọle
pẹlu uniform funfun lọrun rẹ.
“Anti ẹ jọ iranlọwọ yin ni
mo fẹ, ẹ ko ni ri idaamu laye yin. Ẹ jọọ, e ya mi laso ti mo le wo jade nibi.
Ti ilẹ ola ba ti mọ, ma bayin da aso naa pada.”
Omobirin naa wo mi , ko si
fọ esi kankan ju wiwo ti n wo mi lọ. Oro mi se ni kayeefi pupo, eyi ni ko si je
ko mo iru esi ti yoo fọ. O tẹ oju mo mi, bee lo n fi oye gbe idi abajọ ti mo fi
n tọrọ asọ lowo oun. Gbogbo igba yii, ori beedi ni mo wa, ti mo yii aso ibora
mo gbogbo ara mi.
Bee, awon eniyan buruku ti
ba eniyan rere je. Ko ma je wi pe omo obirin yii n wo wi pe mo ni ijamba kan ti
mo fe fi se oun tabi mo ni ohun ti mo fe fi asọ alasọ se.
Tori ohun ti o le ma
mu mi maa beere aso ko ye e rara. Loju re, bi igba ti mo n lo ete ni ọrọ enu mi
jo leti rẹ. Mi o si ri ba wi pelu, aye ti gbẹgẹ. A mo oro mi dabi eni to yagbe,
ti won puro mọ ọ wi pe ko nudi. Eniyan melo lo fe fi idi han wi pe iro ni won
pa?
“Aso?” Ibeere to koko jade
lẹnu rẹ ni yii.
Mo rọ wi pe ko dakun ki o
se iranwo yii fun nitori Oluwa.
Mi o le salaye ohun to
sele gan-an ni pato fun omobirin sisi yii. Ohun ti mo le so ni wi pe aso mi ti
faya koja ohun ti mo le wo sorun, ko si se e dogbon si fun mi, mi o ba ti le
gbiyanju wi wọ rẹ.
Mo fi ara mi si ipo re, mo
si finu ro ohun to seese ko ma ro lokan. Lakoko naa, mo ti ri loju re bi eni wi
pe o n fi oju asewo wo mi.
Bi ko ba ri bee, kini emi
naa n se ni yara ile itura niru akoko bayii?
Gbogbo ohun ti won ba ro
si mi, mo gba a. Ohun oju n wa loju n ri. Ki o sa fun mi laso, ki n rohun wo
jade kuro ninu ile ituara yii.
Omobinrin yii ni ohun o ba
mi mu aso wa niwon igba ti mo ba se ileri wi pe maa daa pada. Mo so fun wi pe
maa ba da aso re pada lowuro ojo keji.
Sugbon omobinrin yii ko
yee teju mo mi. Mo si mo wi pe ko ti ri okodoro oro, idi ti aso mi fi di akisa.
Nigba to je wi pe ohun to daju ni wi pe, ki i se akisa ni mo wo wa.
Kosi mo bi
o se fe bi mi. Tori mo kan wi fun wi pe aso mi faya naa ni. Mo si mo wi pe oju
okan lara awon asewo, oninabi ti won gbe wa si ile itura won ni o fi ma wo mi.
Boya onibara ti o gbe mi
wa lo na mi to si faso ya mo mi lara nigba ti o ba mi sun tan. O ti le ma san
owo fun mi nigba ti o na mi tan. O seese ko je ohun ti n ro lokan re e.
Ẹ tẹsiwaju ninu itan igbesi aye Olabisi K NIBI
0 comments:
Post a Comment