#ayeOlabisiK25
Ẹ le ka itan igbesi aye Olabisi K to ti jade tẹlẹ NIBI ki ẹ to tesiwaju
lati ka eleyii ki itan naa le yeyin daada
Omobirin yii yi pada loju
kan naa lati lo ba mi mu aso ti mo fe wo wa. O ku die ko jade, ni mo ranti wi
pe mi o tile beere oruko adugbo ti a wa. Ati oruko ile itura naa. Omobirin naa
boju wo mi leyin, o wi pe:
“Anti, se e de ro wi pe ko
si nnkan to se yin?”
“Nnkankan ko se mi, mi o kan
mo oruko adugbo yii ni mo se n beere”
“Tori oro yin ko fe ye mi,
mi o gbudo puro fun yin. Ti nnkan ba n seyin e so fun mi ki n tete ba yin pe
awon security.”
“Haa, anti, nnkankan o se
mi o. Ti nnkan ba se mi ma so fun yin. Eni ti emi ati e jo wa sibi lani
gbolohun-aso. Oun lo ya aso mo mi lara. O fogbon gbemi wa sibi ni lo tun wa fe
fi tipatipa ba mi sun. Nibi ti mo ti n dura lo ti fa mi laso ya.”
Omobirin yii ya enu, ko si
le pade. O sun kuro lenu ona to wa, bee lo sun mo odo mi.
“Kilowade ti e o pariwo
fun iranlowo ati wi pe eni naa da?”
“E wo, oro po ninu iwe
kobo. E sa se iranlowo ti e ba le se fun mi na”
“Se ko saa seyin lese sa?”
“Nnkan o se mi. Mo ti pe
enikan to n bo wa ba mi. Eni naa ni mo fe fun ni adiresi ibi, ko le tete wa ba
mi”
Aanu mi se obirin naa
pupo. Bi o tile je wi pe aimoye nnkan ni n be ninu mi ti mi o le so fun. Sugbo
ipo ti mo wa, ibanuje okan, eyi ko le mu mi soro ju ti ye omobinrin yii pelu
alaye die ti mo se fun un.
O fun mi ni address ibi ti
awa yii. Mo si dupe lowo re. O jade lo ba mi mu aso wa. Leyin eyi ni ago mi
dun, nomber oko afesona mi lojade loju ago. Ki ni mo fe wi fun okunrin yii. Mi
o lakoko lati ronu jina, mo gbe ago naa.
“Hello kilosẹlẹ, ibo lowo
wa? Ore mi ti n pe ago e lataaro, emi naa pe ago ẹ ko lọ. Kilosele?”
Mi o tile mo ohun ti mo fe
wi fun un. Mo so fun wi pe alafia ni. Ati wi pe, ma se alaye ohun to sele to
baya. Mo so fun wi pe mo ti ore re ba soro lori ago leyin igba naa, ko si ni i
pe wa ba mi nibi ti mo wa mọ.
Mo pe ago ore oko mi nigba
ti mo ba oko mi soro tan. Mo fun ni adiresi ibi ti mo wa. Ki o to de ba mi, mo
ti paro aso.
Ile tun bo n su si ni ni
ale ojo naa, sugbon ile iwosan ni mo pada sun nigba ti a kuro ni ile itura, emi
ati ore oko mi.
Ẹ tẹsiwaju ninu itan igbesi aye Olabisi K NIBI
0 comments:
Post a Comment