Smiley face

Yoruba Dun: Itan igbesi aye Olabisi K 26



#ayeOlabisiK26

Ẹ le ka itan igbesi aye Olabisi K to ti jade tẹlẹ NIBI ki ẹ to tesiwaju lati ka eleyii ki itan naa le yeyin daada
Yoruba Dun: Itan igbesi aye Olabisi K 26

Inu ore oko mi baje nigba ti mo ro ohun to sele simi fun un. Ohun gan-an lo si mu aba ki a maa lo si ile iwosan wa. Ki won toju mi, ki won fo inu fun mi, ki won si se ayewo ti o ba to. Mo mu ero ti mo fi gba ohun oga mi sile fun ore oko mi.



Igba ti ade ile iwosan, a paro wi pe awon kan ni won fi tipatipa ba mi lopo nigba ti mo n pada lo si ile lati ibi ise. Won beere kilode ti mo fi n fi ale rin, mo paro wi pe sunkere-gbakere oko oju popo lo mu mi mọ igboro.



Awon dokita koko fun mi loogun ti o maa n dena oyun nini. Won ni ki n duro si odo awon moju wi pe ile ti su koja ki n tun maa pada sile. Won ni ti o ba di ni aro ola awon o se ayewo to ba ye, awon o si fun ni awon ogun to ba ye.



Won tun wa fi ohun kan kun un, eyi ti o ba mi leru pupo, won ni awon o se ayewo eje, lati mo boya mo ti ko arun kan tabi beeko. Dokita n ki mi lokan wi pe ki n ma beru, won ni idi ayewo naa ni ki awon le tete mo itoju to ye. 

Dokita gbiyanju lati ma fi gbogbo enu soro, ati lati ma deru ba mi. Sugbon ibi ti ko soro de lo ti ye mi.



Onisekuse eda ni oga mi. Eniyan ko sile ti ibi oju mo eni to ni arun kogboogun HIV. 

Ki o ma lo fi tie koba temi. Olorun ko ma ni je n se agbako aburu o. Abi iru ewo leyi? Ki eniyan ti inu agbada bo si inu ina. Ki eniyan jabo lati ori igi bo sinu iho ejo. 

Eleda mi ma ma sun lọrun o.



Ibi ni ma ti gbe danu duro, mo n bo laipe. E ku etileko. O digba kan naa.



Emi ni ti yin ni tooto.

Olabisi K

Ẹ tẹsiwaju ninu itan igbesi aye Olabisi K NIBI

Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment