Gege bi oro awon Yoruba, won ni arugbo soge ri, akisa logba ri. Yoruba naa lo wi pe, ori taa fi sewe ki i kuro lorun eni ta a ba dagbalagba. Agba wa bura bewe ko ba se o ri.
Igba keji aare ile yii nigba kan ri, Alh Atiku Abubakar, lo gbe aworan atijo re yii sita eleyii to n se afihan iyawo re, Titi, oun, ati ore won kan. Odun 1960 ni won ya aworan naa.
Atiku si salaye akoko naa bi awon se n jegbadun orin King Sunny Ade gege bi okan pataki olorin ti n mu faaji larinrin nigba naa.
Akole ti Turaki Adamawa ko si abe foto naa ni yii:
"I remember how we used to dance to King Sunny Ade's music. You have to know the moves to be cool in Lagosback then"
Se e ko gbagbe wi pe, ana ode yii, 22-09-16, yii ni Sunny Ade pe eni aadorin odun eleyii ti t'oba t'ijoye si ti bere si ni ranse ikini si Oba orin juju agbaye pata.
Pada si ori Atiku Abubakar:
Odun 1946 ni won bi Atiku, ojo karunlelogun osu kokanla odun taa wa yii ni oun naa yoo pe aadorin (70) odun.
Odun 1971 lo fe iyawo re, Titilayo Albert, niluu Eko ni akoko ti Atiku n sise ni ileese asobode ile Naijiria.
Titilayo bi akobi omo re lodun 1972 eleyii ti won pe ni Fatima. Leyin eyi lo tun bi Adamu, Halima ati Aminu.
Gege bi itopinpin Olayemi Oniroyin, awon onwoye oro oselu salaye wi pe, oseese ko je Atiku ni yoo je aare ile yii ni akoko ti Yar'adua bo sori aga ti ki i ba se wi pe, ikunsinu wa laaarin Atiku ati Olusegun Obasanjo.
Ohun kan pato to si fa rugudu aarin won ko ju bi Obasanjo se n pete lati je aare nigba keta leyin to ti se odun merin meji, eleyii ti Atiko tako nigba naa.
Igba ti ero Obasanjo ko jo lo faa ti oun naa fi gbegi dina Atiku to je igbakeji re lati di aare.
E je ka wo okan lara ohun ti Atiko so nipa Sunny Ade lati fi baa yo ayo ojo ibi aadorin odun re:
"From the 1960's to date, Sunny Ade's music will always be timeless. I wish the King many happy returns as he turns 70today."
Olayemi Olatilewa ni oruko mi. Oniroyin ni awon ti won femi n pe mi. Ilu Naija ni mo n gbe, ilu to n san fun wara ati oyin.
Ki Oluwa ko bukun ilu mi lopolopo. Amin
0 comments:
Post a Comment