Smiley face

Hausa àti Fulani ko̩lu ara l’Èkó

Oladeji Kehinde
Inú fu, àyà fu ní àwo̩n ènìyàn agbègbè Agege wà báyìí nìgbà ti àwo̩n è̩yà Hausa àti Fulani s̩àko̩lù tó lágbára sí ara wo̩n ní o̩jó̩ o̩júrú (Wednesday) tí ó lo̩ yìí, tí ènìyan mé̩ta sì tipa bé̩è̩ pàdànú è̩mí wo̩n tí ó kéré tan ènìyàn ogun sì tún farapa yánnayànna.

Kí ó tó di àkókò yìí, bí o̩mo̩ ìyá ni a mò̩ wípé àwo̩n è̩yà méjèjì ma ń bá ara wo̩n s̩e nítorí èdè wo̩n tí farapé̩ra àti è̩sìn wo̩n tí ó papò̩.

Àmó̩ tí ìjà bá ti dé orin a máa dòwe, kò sì oun tí o̩mo̩ ìyá méjì ò lè firawo̩n s̩e tí aáwò̩ bá ti wà láàrin wó̩n, àkókò yìí gan sì ni ès̩ù ma ń lò jùlo̩ láti s̩e is̩é̩ o̩wó̩ rè̩.

Ohun tí a gbó̩ pé ó pilè̩ wàhálà náà nipé ààjo̩ tí ó ń mójútó ìrìna rélùwéè ní ilè̩ yìí lo̩ wó àwo̩n ilé ìpàrùpárù kan tí wó̩n kó̩ sì è̩bá-ò̩nà ojú irin rélùwéè, léyìí tí ó jé̩ tí àwo̩n Hausa, tí ó jé wípé is̩é̩ ká s̩a irin kiri ní is̩é̩ tí áwo̩n ń s̩e tí wó̩n sì ma ń fàbò̩ sí áwo̩n ilé kótópó-kótópó è̩bá ò̩nà náà. 

Àwo̩n Hausa wá fi è̩sùn kan àwo̩̩n Fulani pé àwo̩̩n gan ni wó̩n ni lo̩ gbè̩yìnbe̩bo̩jé̩ fún áwo̩n, tí wó̩n lo̩ só̩ fún ìjò̩ba pé kí wó̩n wó àwo̩n ilé náà nítorí kí wó̩n lè ma rí ààyè dá màlúù wó̩n ká gbogbo agbègbè náà bí ó tí wù wó̩n. 

Ò̩ràn tí àwo̩n Hausa gbà wípé Fulani dá bo̩ àwo̩n ló̩rùn yìí sì ń be̩ ló̩kan wo̩n nígbà tí gbó̩nmisi-omi-ò-to s̩e̩lè̩ láàrin o̩mo̩bìnrin Hausa kan àti o̩kùnrin Fulani míraǹ. Ohun tí a gbó̩ wípé ó s̩elè̩ ni pe Fulani yìí ra oúnje̩ ló̩wó̩ obìnrin Hausa náà àmó̩ kó fé̩ sanwó ní ò̩rò̩ bá di fàmí-n-fàé̩ tí Fulani náà sì bè̩rè̩ sí ní lù ú, lé̩yìn náà ni àwo̩n Hausa dá sí ìjà náà tí gbogbo rè̩ sì di fó̩pomó̩yò̩.


Ìgbà tí ó di nǹkan bí aago kan òru, àwo̩n Fulani lo̩ ká àwo̩n Hausa mó̩lé wó̩n sì pá díè̩ lára àwo̩n è̩èyàn wo̩n. Adìye̩ dàmílóògùn-nù n ó fo̩ lé̩yin ni àwo̩n Hausa fi ò̩ran náà s̩e ti wó̩n kò sì fi ìjà fún O̩ló̩run jà tàbí fi tó àwo̩n o̩ló̩pàá létí.

Bí ó ti di aago márùn-ún ìdájí ni àwo̩n náà ti lo̩ sígun bá àwo̩n atiláawí padà tí ìjà ńlá míràn sì tún bé̩é̩lè̩. Wó̩n s̩e àwo̩n Fulani lés̩e dáadáa, ò̩pò̩lo̩pò̩ nǹkan ni wó̩n sì bàjé̩. Ìjà náà pò̩ gidi ni títí di ojúmó̩ tí ìbè̩rù ńlá sì mú gbogbo àwo̩n olùgbé agbègbè náà.

Bó tilè̩ jé̩ pé àwo̩n Hausa kò̩ láti bá akò̩ròyìn Punch tí ó wà níbi ìs̩è̩lè̩ náà sò̩rò̩, ò̩kan lára wo̩n tí ó kò̩ láti so̩ orúko̩ ara rè̩ só wípé "wo̩n ti pa mé̩ta lára àwo̩n èèyàn wa a ò sì ní so̩ jù bé̩è̩ lo̩, tí ó bá tó àkókò a ó pé è̩yin oníròyìn".

Nígbà tí ó ń sò̩rò̩, agbe̩nuso̩ àwo̩n o̩ló̩pàá, Dolapo Badmos, so̩ wipé èèyan kan ni ó kú nínú ìs̩è̩lè náà. O ní "nǹkan bí ago kan òru ni a gba ìpè pàjáwìrì pé ìjà ń s̩e̩lè̩ láàrín àwo̩n è̩yà méjì náà tí o̩ló̩pàá Area G, RRS àti àwo̩n ti Abattoir sì sáré lo̩ síbè láti mú kí àláfíà ó wà".






Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment