Smiley face

Yoruba Dun: Itan igbe aye Olabisi K (36)

#ayeOlabisiK36

Inu mi ba jẹ, mo si tun bẹrẹ ẹkun ni sisun. Mo sukun oju mi wu, bee mi o rẹni rẹmilekun. Igba to ya, mo lo fi omi bọ oju mi, mo si gba ile orẹ ọkọ mi lọ ni irọlẹ ọjọ naa. Mo ko alaye mo ro fun un.
O ni a je wi pe ọrọ ti a ni ki baba mọ gbọ, baba naa ni yoo pada pari ẹ nu-un.


O beere nipa agbẹjọro ti o fẹ ran mi lọwọ. Mo sọ fun wi pe mi o ti gbo abọ rẹ. Ati wi pe mi o ti mo boya agbẹjọrọ naa setan lati ran mi lọwọ.

Ọrẹ ọkọ mi naa fi mi lọkan balẹ wi pe oun naa ko duro, oun kan fẹ mọ boya agbẹjọro naa setan lati ran wa lọwọ ni.


O ni ti o ba kọ, o ni ọna abayọ miiran wa. Mo dupe lowo rẹ, o fun mi lowo moto ki n fi pada sile. Mo deba iya mi, mo si ko ẹjọ mo ro fun awon naa. Iya mi naa fi mi lọkan bale wi pe awon ko duro lori oro mi.



Won ni ni agbara Olorun, oga mi o pada jebi ni. Iya mi ni o oun yoo maa ba mi soro to ku to ba ya. Won rọ mi ki n jẹun. Gbogbo wa jeun asi bo si ori ibusun.



Ori ibusun ni mo wa, mi o le sun, ironu ko jẹ. Bi eniyan ba n wa iranse esu ti ko ba ri, o ni lati jẹ wi pe ọga mi yii gan-an lẹni ti wọn ọn wa. Abi iru eniyan wo leyii? Ibo ni mo fe ba yara ja?


Mi o le toju iya mi mọ bi ti tẹlẹ, iwonba owo ti iya oniya n ri, lo tun fi n ba mi sare kiri ki n ba le ma dero ẹwon. Kosi oluranlowo kankan afi Olorun.

Gbogbo awon ẹbi iya mi ti sa fun wa nigba ti won ri wi pe nnkan o senu-ire fun wa. Won sa ka maa ba gbe bukata ti wa lewon lorun.

Sebi won ni awon abanijafeto omoniyan wa. Ibo gan-an ni mo tilẹ mo ti mo le wa won si. Boya tilẹ ba mọ, ma ba ore oko afẹsọna mi sọ. Ko je ka tọ awon ajafeto ẹni lọ.

Sebi won ni won ki i gbowo, ise ilu ni won se. Amọ kilode ti ero yii ko ti so si mi lokan lati ijo yii wa.


Boya ìyà kò ba ma ti jẹ mi debi to je mi de yii.

Amo sa, o ba ni naa ni ko ti baje tan.


Bi orisiirisii ero se n wa si mi lokan re e. Mi o le so iye ago to lu tori wi pe ko si ina ti mo le fi ri ago ẹgbẹ ogiri. Amọ mo mọ wi pe ọjọ ti lọ gan-an, a si ti n sun mo aajin.


Gbogbo ẹ ti pa lọlọ bi iboji oku. E mi gan-an o tile mọ igba ti orun gbe mi lo.

Sugbon mo sakiyesi wi pe afẹfẹ tutu kan rara n yo wole lati oju ferese eyi to si n mu oju mi toogbe.
O si n tẹsiwaju...















Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment