Smiley face

Ile-ejo ran awon meji ti won ji batiri foonu lewon odun mefa

Kehinde Oladeji

Ile-ejo majisireti Oredo ni Benin ti ran Happy Okotie àti ore re Kingsley Ebose ni ewon Odun mefa lai anfani beeli lori esun ole jija.

Awon eni afurasi meji naa ni won wu iwa buruku yii ni ojo keedogbon, osu ti o koja, ni  ijoba ibile Oredo, New Benin, nigba ti won fo ile ikerusi okunrin kan ti won pe oruko re ni Tessy Okpebiye, ni oru ti won si ko awon nnkan ti owo won to ninu iyara naa.

Awon nnkan ti Tessy so wipe won ji ninu iyara ikerusi naa ni; batiri Nokia kan, foonu Samsung Galaxy meji, ero konputa alagbeeka (Laptop) àti owo ti o to egberun metadinlogun(17,000).

Abanirojo fun awon agbofinro ti o ka esun naa si awon odanran naa lese ni kootu, ogbeni Patrick Agbonifo, so wipe, gbogbo ohun ti won ji naa ni iye owo re to egberun lona igba o le marunlelogbon.

Adajo ile ejo majisireti naa, arabinrin RacheaI Ogbevoen, ti wa ni ki awon odanran meji naa o lo ma sinmi ni ogba ewon fun odun mefa pere.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment