Smiley face

Oni ni Sani Abacha ko ba sojo-ibi odun metalelaadorin (73) ti ki i ba se tiku

Oni yii, ogunjo osu kesan-an odun 2016 ni Ogagun Sani Abacha ko ba pe eni odun metalelaadorin (73) laye ti ki i ba seku to mu lo lojo kejo osu kefa odun 1998.

Aheso oro kan fo nigba naa to so wi pe, eso Apple lo seku pa olori orileede Naijeria to je laaarin odun 1993 si 1998, eleyii ti a ko reni to tako aheso naa titi di akoko yii.


Iwadii Olayemi Oniroyin fidi re mule wi pe, omo ilu Borno ni Sani Abacha, o kan dagba silu Kano lasan ni. Sugbon o gbile nilu Kano to bee gee to fi je wi pe ko seni takoo wi pe ki i se omo ilu naa. Ilu Kano sini ibi ti ibujoko awon ebi re wa leyin iku re.

Koda, leyin iku Abacha, okan ninu awon omo re ti gbiyanju lati je gomina ipinle naa sugbon ti ero re ko kesejari.


Ninu iwe akosile awon olori orileede ile adulawo ti won bayeje julo, nipa iwa jegudujera ati tite eto omoniyan mole, oke ni oruko oko Mariyamo wa.

Siwaju sii, bi o tile je wi pe aimoye owo ni baba Muhammed jiko nigba aye re, eleyii ti ile Naijiria si n gba ti won ko si ti gba tan, akosile fihan gbangba wi pe, eto oro aje ile wa gbayi ni awon akoko isejoba re.

Arise larika, arika si ni baba iregun. Ohun ti gbogbo wa ba se lonii ni yoo ditan bo dola.

Olayemi Oniroyin ni oruko mi, rere ni emi o ma se, mi o ni seka.

Nje eyin gbo wi pe ogbeni Jemiisi Faleke ti n dupo gomina nipinle Kogi ti pada jebi nile ejo to gaju lo lonii niluu Abuja?

Agogo ogbon: eniyan ti ko ba ti gba kadara, yoo pada gba kodoro.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment