Ojo kejilelogun osu kesan-an odun 1946 ni won bi Sunday Adeniyi si ile aye. Eyi lo si mu pe eni aadorin (70) odun lonii (22-09-2016).
Gege bi iwadii Olayemi Oniroyin, ilu Osogbo oroki omo asala ni won bi Sunday si sugbon omo bibi ilu Ondo ni i se.
Sunday Adeniyi naa ni won tun mo si King of Juju, Sunny Ade ati Minister of
Enjoyment.
Moses Olaiya ti gbogbo eniyan mo si Baba Sala ni Sunny Ade koko n tele kiri ko to di wi pe o daduro, to si lo da egbe tie naa sile.
Odun 1967 ni Sunny Ade da egbe orin re sile. Aimoye igba lo si ti paaro oruko egbe orin re.
Gege bi akosile itan ti Olayemi Oniroyin rigbamu, awon onise lameeto orin (music critics) salaye Sunny Ade gege bi olorin to kangun si Bob Marley lodun 1982. Eleyii si fihan bi orin re se je itewogba lagbaye
Orin ti Sunny Ade yoo koko gbe jade lo pe akole re ni "Challenge Cup." Eleyii to se lati fi se igbelaruge fun boolu alafesegba abele Naijiria. Orin naa si je lo ni akoko naa gege bi a se gbo.
Awo orin re to gbe jade lodun 1998 to pe ni ODU wa lara awon orin ti won yan lati dije ninu ami-eye Grammys to maa n waye niluu Amerika.
Ninu itan mii ti ko tun se yipada, Sunny Ade ni yoo je onkorin ile adulawo akoko ti yoo jumokorin pelu onkorin ile Amerika eleyii to waye lodun 1984 pelu Stevie Wonder.
Lara aseyori oba orin juju ni bo se se idasile ileese redio re siluu Ondo to pe ni M & C Redio
Yato si eleyii, awon onwoye salaye Sunny Ade gege bi okan lara awon olorin to lenu-loro julo lagbaye ti a ba n so lagbo olorin igba iwase ati titi de aye ode oni.
Bi o tile je wi pe aimoye obirin lo bimo fun Sunny Ade, sugbon meje lale pe ni iyawo re, eleyii to fe nisu-loka.
Aadonrin odun ki i se wasa, gbogbo wa pata laba omo Adeniyi yoo fun bi Oluwa oba se dasi. Adura wa fun baba 70 ni aleekun alaafia, ayo, idunnu, ilera, ati itesiwaju, Amin.
0 comments:
Post a Comment