Kehinde Oladeji
-Won ni tori obinrin naa loyun fun ni o se fe e
Ibrahim Chatta, ti awon ololufe re tun ma n pe ni Baba Tapa, ko se igbeyawo naa ni alariwo rara, ohun ti awon eeyan so wipe o fa eyi ni wipe oju n ti okunrin naa nitori obinrin keta ti o ma fe niyen.
-Won ni tori obinrin naa loyun fun ni o se fe e
Bi aheso ni oro naa se koko ru sita ni ose meji seyin wipe gbajumo
osere n ni Ibrahim Chatta fe gbe iyawo tuntun, amo ni ayajo ominira ti o
lo, iyen ojo kinni osu ti a wa yii, ni osere naa pa awon elegan ati
alaheso lenu mo nigba ti o gbe ololufe tuntun ti oun naa je osere tiata,
Laide ti opo eeyan mo si Lizzie Berry, niyawo.
Ibrahim Chatta, ti awon ololufe re tun ma n pe ni Baba Tapa, ko se igbeyawo naa ni alariwo rara, ohun ti awon eeyan so wipe o fa eyi ni wipe oju n ti okunrin naa nitori obinrin keta ti o ma fe niyen.
Ooto ni won so,
won o paro mo o, iyawo keta re e ti Ibrahim ma fe. Odun 2008 ni o koko
fe iyawo re akoko ti oruko n je Olayinka Solomon, ti iyen si bimo kan
fun un ki o to di wipe igbeyawo naa daru.
Ohun ti omobinrin naa
so wipe o fa ipinya won ni wipe, Ibrahim o mo obinrin toju rara, gbogbo
igba si ni o ma n lu oun ni alubami.
O ni koda, gbogbo owo owo
oun ni Ibrahim gba tan tori owo oun gbe soke ju tie lo nigba naa, igba
ti o di wipe nnkan safere lowo oun ni o bere si ni yo owokowo, ti a ma
kanra mo oun ti o si tun ma n gbe awon ale e wale ki o to di wipe awon
wa pinya. Okunrin onisowo omo Ibo kan ni a gbo wipe Olayinka n fe bayii.
Bi
oro yii ti de eti Baba Tapa ni oun naa ti yara ro awijare tire ti o si
so wipe " iro ni Olayinka pa mo mi o, emi o ki n na obinrin, bee ni mi o
si gba owo lowo e. Idi ti mo fi ko o sile ni wipe, iyawo mi kii gbele,
bee si ni ko ki n moju to omo wa Malik, ki enikeni ma da mi lebi rara".
Sebi ti obinrin ba koni, obinrin naa niyan ma fe, bee si ni ko je tuntun fun awon elere tiata lati ni ju igbeyawo kan lo.
Igba
ti o di Odun 2012 iroyin gbagboro pe Ibrahim Chatta ati Salamatu
Lafiaji, omo gomina ipinle Kwara ana, Shaaba Lafiaji, n se wole wode àti
wipe won ti n palemo ati se igbeyawo alarinrin.
Ipari odun naa
gan ni awon ololufe mejeji se igbeyawo onilana musulumi. Pepeye ponmo
lojo inawo naa, opolopo awon olowo ile yii ni o wa nibe ti won si fun
won lebun lorisirisi.
Opo awuyewuye ni o bere si ni jade leyin
igbeyawo naa ti awon kan si n so wipe awon tokotaya naa o ni pe tuka bi
awon omowewe ti n sere osupa.
Looto, asotele naa se mo Ibrahim ti awon eeyan ti n pe ni ana gomina ati iyawo re Salamatu lara.
Ohun
ti a gbo wipe o fa ituka naa ni wipe, Ibrahim ko lowo ti o to lati fi
gbo bukata Salamatu omo baba olowo. Igbe aye surulere ti Chatta n gbe o
ba omobinrin naa lara mu tori omo ti won bi ni idile olorunsogo ibi si
ti wahala ti bere niyen.
Bakanaa ni won awon ti o sunmo ebi naa
so wipe nise okunrin onitiata yii ma n lu omo gomina naa, eyi si pelu
nnkan ti o mu ki awon mejeji jawe funra won ti onikaluku si n je oruko
baba e.
Boya nitori itiju àti bi awon aye ti se n ka obinrin si i
lorun ni ko je ki Ibrahim Chatta o gbe oro ife oun Lizzie sojutaye, tori
ko seni to gbo pe awon mejeji n fera titi di ose kan si igbeyawo won.
Amo ohun ti a gbo ni wipe omobinrin naa ti loyun fun un tori naa ni won
se pa a lariwo.
E gbadura pe ki olorun je won bara kale o.
0 comments:
Post a Comment