Smiley face

Tori owu jije, obinrin dana sun Iyawo oko e pelu oyun ninu.

Kehinde Oladeji

Ti won ba sadura fun un yin pe e o ni gbele funro ro ki e ya ma sami e witiwiti.

Opo eeyan ni o je wipe inu ile won gan ni iku ti yoo pa won ti wa ba won, iru e ni ti alaboyun osu meta kan ti o fere jona guruguru mo inu ile oko e nigba ti omobinrin kan wa ka a mole ni osan gangan ti o si da petiro si i lara ti o si tun sana si lori esun wipe o gba oko oun.

Omobinrin alailaanu naa ti won pe oruko ni Lami Clement, eni odun mejilelogun, ti wa ni agodo awon olopaa ipinle Bauchi nibi isele buruku naa ti sele, nibi to ti n so fun won ohun to ti i wu iwa apayan naa, ti ko si ro ti eje orun ti o wa ninu Amina mo lara ki o to dana si lara bii okete.

Ohun ti a gbo ni wipe, Lami lo si ile eni ti o pe ni afesona re ojo pipe, iyen Mustapha Ayodele, lati lo dana sun awon ile re ati awon eru inu e nitori onitohun ko o sile ni ojo pipe seyin ti o si lo fe elomiran.

Igba ti obirin asekupani yii de ile naa, ko ba eni ti o wa lo amo o ba Amina ti o gbagbo wipe oun lo gba eni ti o ye ki o je ade ori oun, layi besubegba, o tu agolo petiro owo re si omobinrin naa lara o si sana si, leyin naa ni o tilekun mo o ti o si salo.

Ariwo ina ni awon aladugbo gbo ti won fi sare wa si ilekun fun Amina amo ti ina naa ti jo o ni oju, apa àti itan. Ile iwosan ni Amina wa bayii nibi ti o ti n gbawosan ti o si n sope fun Olorun wipe emi oun o bo.

Nigba ti o n soro fun awon agbofinro, Mustapha Ayodele oko obirin alaboyun naa so wipe "Ibise ni mo wa nigba ti won pe mi wipe ile mi n jo, igbati mo ma de ile mo ba iyawo mi ti o n jerora ninu ina, emi ati awon aladugbo mi si sare gbe lo si ile iwosan fun itoju.

Ooto ni wipe Lami feran mi ti o si fe ki a ma ferawa amo emi o nife e a o si figbakankan ferawa ri, bi o se wa so wipe mo ja oun kule fe elomiran ni ko ye mi".

Alukoro olopaa ipinle Bauchi ti o jeri si oro naa nigba ti o n ba awon oniroyin soro so wipe, dukia ti o to egbegberun naira ni o jona ninu isele naa owo si ti te arabinrin yii yoo si foju ba ile ejo laipe.
Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment