Smiley face

O ma se o! Leyin ti igbeyawo won ku osu kan, oko fi ina gbe Iyawo e ninu ile won.

Kehinde Oladeji

Afi ki gbogbo eni ti o da ojo ayeye pataki sona o ya ma gbadura pe ki nnkan ti yoo ba ojo ayo naa je o ma sele.

Inu ibanuje nla gbaa ni ebi Loretta Ewere, eni odun marundinlogoji, wa bayii lori bi omo won ti o ye ko segbayawo ni osu to n bo yii se ku si ile oko afesona re ni agbegbe Ajoke Kazeem, ni Idimu, Eko.

Ohun ti a gbo ni wipe, Loretta ti n gbe ni odo afesona re ti won pe oruko re ni Segun Tolani lati bi odun merin seyin leyin ti won ti se eto momi-n-mo-e, osu ti o n bo yii si ni o ye ki won se igbeyawo alarinrin ki ijamba buruku yii to sele.

Omo Ekiti ni Tolani ti afesona re si wa lati ipinle Delta amo ebi awon mejeji faramo ibasepo won lai wo ti eya tabi ede won si ti n ba won palemo fun igbeyawo won paapaa, lai mo wipe ohun ti yo ba ojo ayo won je ti n kanlekun.

Ohun ti o sele gan ni wipe, ina monamona inu iyara Tolani baje lojo naa, nigba ti NEPA si muna de ina iyara tire nikan naa ni ko tan.

O ranse pe eni ti o ma se e onitohun si ni ki o san egberun meji abo naira (#2,500) amo boya nitori bi ita se ri lowo yii lo mu ki okunrin naa wo wipe owo naa po ni o ba ni oun gan le se ise naa funra oun.

 Tolani gbe akaba ti ina re ti o baje o si ni ki Loretta o ba oun di akaba naa mu ki oun ma baa subu, amo asise ti omobinrin naa se ni wipe o fi owo kan di opo onirin kan ti o sunmo odo e mu ti o si fi owo keji di akaba mu fun oko e. 

Ibi ti onitohun  ti n se ina loke ni waya kan ti o ni ina lara ti jabo lowo e ti o si kan rin ti omobinrin naa di mu, bi ina se gbe e niyen.
A gbo wipe enikan ti isele naa soju e gbiyanju ati fi owo fa omobinrin naa kuro lara opo ti o gan mo amo ti ina naa ju oun paapaa sigbo.

Awon ara adugbo sare lo pe eletirisa wa ti o lo po ina naa lati ibi orisun re ti Loretta si subu ti o si tun fori gba ori konkere.
Awon eniyan gbiyanju ati doola emi e pelu opolopo miliki amo omobinrin naa ti dagbere faye.

Gbogbo awon ti o gbo oro ohun ni o ti n sepe le oko naa ti won si n bu u pe iwa ahun e ni o fi pa afesona e naa tori ko ye ki o lo ma se ina funra re lai mo nipa ise naa.

Latigba iroyin iku Loretta ti tan ni awon ore re paapaa julo awon ti won jo lo si ile iwe Poli Ibadan nibi ti o ti kekoo-karakata ti n so orisirisi oro iwuri ati ibanikedun nipa re lori ero ayelujara, awon miran o si gbagbo wipe arewa omobinrin naa ti kuro laye patapata.











Share on Google Plus

About Olayemi Oniroyin

0 comments:

Post a Comment