Ohun tí a kò bá mò, bí idán ni àwon àgbà so pé ó máa n
rí, Àti pé ohun tí a kò bá rírí ní n seni ní kàyéfì. Bí a ó bàá sojú abe
níkòó nípa òrò ètò èkó láwùjo Yorùbá, adire wa ti n je àjeyó bámúbámú
saájú kí àgbàdo àwon òyìnbó tó dé(bí ó ti lè se pé ïlànà ìkékòó ìbílè
yàtò sí ti ìgbàlódé).
Àbájáde ìwádìí àti ìtopinpin mi fihàn wí pé Ogbón "ìtúnasolépaláró gberojà bíi titun" ni àwon Òyínbó lò fúnwa nípa àwon èkó tí à n kó ní àwon ilé èkó gíga wa gbogbo. Èrí láti fi gbe àlàyé mi lésè rè é;
* Èkó ilé
* Ìkíni
* Isé Àbáláyé
Ni àwon òyìnbó pòpò di EDUCATION.
…………………………
* Àsà ìranra- eni-lówó (Èsúsú, Àjo, Èbèsé,Àáró, òwè àti Àrokodóko)
* Ìwòfà yíyá
Ni àwon òyìnbó pa láró di BANKING AND FINANCE.
………………………………
* Egbé kíkó
* Ètò Ìgbéyàwó
* Ètò Ìsomolórúko
* Ètò òkú sínsin/Ogún pínpín
* Ètò Ebí/ Àjobí
Ni wón jànpò sínú èkó tí wón pè ní SOCIOLOGY
…………………………
* Ìgbàgbó Yorùbá nínú Olódùmarè/ Òrìsà
* Ìgbàgbó Yorùbá nípa Orí/àyànmó/kádàrá.
* Ìgbàgbó Yorùbá nínú àlá.
* Ìgbàgbó Yorùbá nípa òkú òrun
Ni wón kójo sínú ìmò PSYCHOLOGY
………………………………
* Orírun àwon Yorùbá
* Àwon odún ìbílè: Olójó, Òkè Ìbàdàn, Olúmo, Ojúde Oba,Òrànmíyàn abbl
Ni wón dìpò sínú ìmò tí wón pè ní ANTHOLOGY.
………………………………………
* Ìgbàgbó Yorùbá nínú òògùn, àyájó àti ofò ni òpá ìtilè èkó MEDICINE
………………………………………
* Ìtójú ilé àti àyíká
* Eré ìdárayá àbáláyé ( Eré jèlènké àti eré jàgídíjàgan)
* Oúnje ilè wa(jíje ní tútù, sísun, díndín, yíyan àti bíbò/ sè)
Ni wón hunpò sínú èkó PHYSICAL/ HEALTH/ NUTRITION EDUCATION.
………………………………………
* Ìgbàgbó Yorùbá nípa àsèyìnwáyé àbíkú/Emèrè/ Àkúdàáyà.
* Ìgbàgbó Yorùbá nípa ìsèdálè àgbànlá- ayé.
* Ìgbàgbó Yorùbá nípa èmí àìrí ni wón fi se àtègùn fún èkó MYTHOLOGY.
……………………………………
*Àwon Orin àbáláyé ( Orin èsìn àti Orin ayeye)
* Isé onà síse (gbégilére,Aso híhun, Aró dídá, igbá fínfín)
Ni wón so di èkó ART/ MUSIC.
……………………………………
* Ètò Ìsejóba
* Ipò Oba àti àwon ìjòyè
* Àwon èèwò ilè Yorùbá.
* Àjobí (Alájobí)/ Àjogbé ni àwon òyìnbó fi se àkàbà àmúgùn fún èkó tí wón pè ní LAW/ GOVERNMENT.
Sé e wá rí i báyìí pé, àwa gan-an la ò mo iyì ara wa tí a fi n pe igbá iyì àti èye tí oba òkè fi jinki wa ní pankaara, tí àwon èyà mìíràn fi n pèé ní ìkólè. Àsà tó gba iyì gba èye, ìmò tí n máyé rorùn lOba òkè fi ta wá lóre láwùjo Yorùbá. Èyin ni kí e jé kí á mo iyì ara wa.
Àsà àti Èdè Yorùbá kò ní dàtèmérè.
Ayé wa náà ò ní pin yìnkìn.
Àse Èdùmàrè
Orisun ©Olùkó Èdè àti Àsà Yorùbá Arb (2016)
0 comments:
Post a Comment