Lanre Teriba |
Awon Yoruba bọ, won ni ọdẹ to pẹran to setutu nitori eyi ko nitori omiran ni. Ogbontarigi olorin ẹmi, Lanre Teriba, ti gbogbo eniyan tun mo si Atorise, ti gbe ohun ọpe soke si Oluwa lẹyin aseyori iyide orin rẹ to waye niluu Amerika.
Atorise ati Olu-Omo Promotions |
Atorise ko sai tun dupe lọwọ agbatẹru irinajo iyide orin rẹ naa, Olu-Omo Promotions, fun atilẹyin nla to se fun-un.
Ẹkunrẹrẹ alaye ni yii lẹnu Ajinhinrere Lanre Teriba...
Wayio, ariya ikinni kaabọ Lanre Teriba lati ilu Amerika yoo ma waye lọjọ ketadinlọgbọn osu kọkanla odun yii niluu Eko. Alaye ni yii ni salẹ
Igbiyanju lasan lẹda le se, alubarika wa lọwọ Eledumare Ọba. Adura wa ni wi pe, Olarenwaju Atorise ko ni pada dero ẹyin. Olu-omo kosi ni di arisunkun lase Yaradu loke. Asẹ
0 comments:
Post a Comment