Òní kọ layé ti mọ Kemi Olunlọyọ gẹgẹ bi oniroyin kan ti
ki i ye da awuyewuye silẹ ni akoko ti isẹ iroyin rẹ ba jade. Kemi, ọmọ gomina ipinlẹ
Oyo nigba kan ri, Oloye Victor Omololu-Olunloyo, lo ti pe baba rẹ ni alainilaakaye ẹda pẹlu bo se da si iroyin rẹ kan to gbe jade nipa ọmọọba Jide Kosoko
Alaye ranpẹ:Gege bi iwadii Olayemi Oniroyin,ti won ba pe eniyan ni alainilaakeye, ohun to tunmo si ni yii:Alainilaakaye eniyan ni ẹni ti ko lọgbọn, olódo, ọ̀dẹ̀, alailọpọlọ, dindinrin tabi alaini oye lori.
Ninu iroyin to da awuyewuye silẹ ni eyi ti Kemi Olunloyọ gbe jade lẹyin iku Henrietta Kosokoeleyii ti n se iyawo ẹlẹẹkẹta ti yoo ku nile Kosoko. Kemi to ti fi igba kan gbe
niluu Canada ri se alaye ninu iroyin rẹ wi pe, o seese ko jẹ wi pe ọkunrin
osere onitiata naa n fi awon iyawo rẹ bọri tabi soogun ni.
Jide Kosoko |
Bakan kan naa lo n pe fun iwadii to jinlẹ nipa ọrọ naa lati
mo nipa ohun ti n sokunfa bi awon iyawo se n ku nile Jide Kosoko.
Jide Kosoko ko so ohunkohun ni awon akoko naa ayafi awon kan
bi Dayo Amusa ti won wọ iya-ijakadi lori ayelujara pelu Kemi nipa isẹlẹ naa.
Leyin ti gbogbo eniyan ro wi pe ọrọ naa ti rodo lọ momi ni
jide pada sọrọ wi pe, baba akoroyin naa, Oloye Victor Omololu Olunloyọ ti wa
tọrọ aforijin nipa awon ọrọ kobakungbe ti ọmọ rẹ n sọ kaakiri.
Henrietta Kosoko |
“Kemi fi èrò rẹ han lasan ni, eleyii to lẹto si. Ọpọ awon eniyan naa ni won on sọ katikati lẹyin sugbon Kemi kan wa sọ tiẹ ni gbangba ni. Sugbon ohun to jaju ni wi pe, baba ọmọ naa ti wa tọrọ aforijin lọwọ mi”- Jide Kosoko
Ohun ti baba Kemi Olunloyo se yii ko ba ibi to dun rara lara akoroyin
naa. Eleyii lo si mu pe baba re ni alainilaakaye ẹda pelu bo se dasi isẹ iroyin rẹ. O ni o yẹ ki oye o ye
baba oun wi pe isẹ oun ni loun se gege bi oniroyin. Alaye arabirin naa ni yii:
“Baba mi Victor Omololu Olunloyo gẹgẹ bi alanilaakaye eniyan ni lati lọ ma rawọ ẹbẹ si awon ilumọọka latari isẹ iroyin mi lori ayelujara jẹ ikoja-aye gbaa.Ohun kan ti ko ye baba mi ni wi pe, ise iroyin ati ise lamẹẹtọ iroyin ayelujara ni isẹ ọwọ ati isẹ òòjọ́ mi.”-Kemi Olunlọyọ
Kemi tun tesiwaju lati so
wi pe, baba oun wa lara awon ti won korira ojulowo isẹ iroyin to gunle ododo.
Ko sai mẹnuba diẹ ninu itan nipa bi baba rẹ se gbogun ti ile isẹ iroyin ipinlẹ Ọyọ
(BCOS) ni awon akoko kan seyin ni ona lati pana awon iroyin òdodo.
Lakotan, iroyin iku Henrietta
Kosoko wa lara awon iroyin to mi agbo amuludun Naijiria lodun 2016. Iroyin yii
kan naa lo si mu oruko Henrietta Kosoko wa lara awon oruko osere ti awon eniyan
sawari julo lori ero google fun odun 2016.
Okan ninu awon omo oloogbe naa, LT, korin lati fi se ìdárò mama won to lo simi, orin yii naa ni n fi ma kadi rẹ nilẹ.
Adura mi ni wi pe, Edua yoo ba wa dawọ ibi duro nile Kosoko ati lagbo amuludun ile Naijiria.
Adura mi ni wi pe, Edua yoo ba wa dawọ ibi duro nile Kosoko ati lagbo amuludun ile Naijiria.
0 comments:
Post a Comment