Ilẹkun ile isẹ iroyin ti ja sọnu |
Ọkan ninu awon
ololufẹẹ mi lori facebook gbiyanju lati ba mi takurọsọ lana. Mo se akiyesi wi
pe sọrọsọrọ ori afẹfẹ ni ẹni naa. Leyin taa kira wa tan. O beere wi pe,"
se oniroyin ni mi looto?'
Sẹ ẹ mọ wi pe "Olayemi Oniroyin” ni
oruko mi. O wa fẹ mọ boya mo n jẹ ẹ lasan ni a bi isẹ ti mo n se ni.
Mo dahun
wi pe bẹẹni. Leyin naa lo tesiwaju lati beere ile isẹ iroyin ti mo n ba sisẹ.
Igba yii ni oye ibeere rẹ akọkọ wa ye mi kedere. Mo sọ ile ise iroyin ti mo ba
sise fun-un.
Sugbon ibeere naa tun bọ fun mi loye ohun
ti awon eniyan gba gẹgẹ bi ojulowo oniseroyin. A ko le mo ojulowo oniroyin nipa
wi pe irufẹ ẹni bẹẹ n ba ile ise iroyin kan sise nipato. Gbogbo ẹni irun ori rẹ
takoko kọ lori rẹ buru. Gbogbo alangba to dakundele si ko ninu un run.
Gege bi oye kekere mi, mi o gba wi pe
gbogbo ẹni ni anfaani lati sise labẹ ile isẹ iroyin kan pato lojuwo oniroyin.
Bakan naa ni mi o so wi pe gbogbo awon osise ile ise iroyin lòpè.
Sugbon pataki ohun to ye ko ye wa ni wi pe,
awon nnkan wonyi ko ni eniyan fi n mọ oniroyin gidi.
Ohun to se afihan ojulowo onise iroyin ko
ju bi ise ọwọ rẹ se tewon si lọ, imo to ni, agbekalẹ ati akojopo iriri ogbon ti
fi n se bi ọlọba.
Nnkan ti yipade si igba iwasẹ, to je wi pe
bi eniyan ko de ilu Oyo, a ko le gbọ ohun ti Alaafin wi. Ọlaju ti de, aimoye ẹrọ
igbalode ti so aye dẹro.
Ko pa dandan ki eniyan to le wa labẹ ile ise iroyin kan
ka to le gba wi pe ojulowo onise iroyin ni. Orisiirisii anfaani lo ti si silẹ
eleyii to fun awon akikanju onise iroyin lati gbe ogidi ise ọwọ won jade lai si
ibẹru tabi ifoya.
Ẹ jẹ ki n tun sọ daada, ọpọ awon ile ise
iroyin lo je wi pe won ko jabọ ojulowo iroyin mo fun awon ara ilu latari iberu.
Idi ti nnkan bayii si fi n waye ko se leyin wi pe, pupo ninu awon ile ise
iroyin yii loje ti ijoba ati awon oloselu.
Awon ile ise iroyin to je ti olokoowo
gan-an beru ki awon alagbara ma pana okoowo won. Awon ile ise iroyin to
dangajia lojẹ awon ile isẹ to je wi pe ojulowo oniroyin lo da won silẹ lati sise
iroyin gege bo ti ye.
Mo si n tesiwaju...
0 comments:
Post a Comment